ISE ISIN ONIGBAGBO
Ogbon Àti Ìròtélè
Bí Nehemiah tilè ti ń wá ìrànlówó Olórun, sùgbón síbè kò káwó gbera kí a wá máa rò wípé òun kò ní ojúse kankan mó láti se nínú isé tàbí èròǹgbà láti tún Jérúsálémù kó. Pèlú ogbón àti ìròtélè tó wuni jojo, ó tèsíwájú láti se gbogbo àwon ètò tó lè mú kí isé náà jé àseyorí. Ó sì ń gbé gbogbo ìgbésè kánkán pèlú èmí ìṣọra.—The Southern Watchman, Mar. 1, 1904. IIO 239.2
Àpeere okùnrin mímó yìí (Nehemiah) gbodò jé èkó rere fún gbogbo ènìyàn Olórun, wípé àdúrà gbígbà pèlú ìgbàgbó nìkan kò tó, bíkòse isé takuntakun pèlú òdodo. Mélòó mélòó ìgbà ni a ti bá ìsòro pàdé pẹ̀lú ohun ìdíwó nínú isé pàtàkì yìí nítorí tí a kò ka ogbón, ìròtélè àti ìfaradà sí nínú isé ìsìn. Eléyìí jé àsìse ń lá. Ó jé ìse wa láti sa gbogbo ipá àti agbára wa èyí tí yóò mú wa jé òsìsé pàtàkì tí ó kún ojú òsùwòn fún Olórun. Síse àbojútó fíní fíní àti gbígbé ètò tí ó múná dóko kalè se pàtàkì fún àseyorí isé Olórun gégé bí ó ti rí ní ìgbà Nehemiah.—The Southern Watchman, Mar. 15, 1904. IIO 239.3