ISE ISIN ONIGBAGBO

237/273

Ní Ìdiwòn Rere

Òpòlopò àwon tí a pè láti sisé títayo má ń se kékeré nítorí tí wón gbìyànjú kékeré. Egbegbèrún ni ó gbé ayé bí eni pé wón kò ni ipa kan fún ìgbé ayé, ìdiwòn ń lá kò sí láti se. Ìdí kan fún èyí ni pé wón fi ojú témbélú wo ara won. Kristi san owó iyebíye lórí wa, fún ìdí èyí, Ó fé ká mo rírí ara wa.—Gospel Workers, p. 291. IIO 238.3

Ní gbogbo ìgbà tí Jésù wà láyé, Ó jé eni tí ó ń sisé déédé pèlú ìtara. Ó ń fé òpòlopò, Ó sì gbìyànjú lópòlopò.—The Desire of Ages, p. 72. IIO 238.4

Àwon tí ó ń sisé fún Olórun nílò ìrírí tí ó ga, tí ó jìn tí ó sì pé ju èyí tí àwon ènìyàn kò ronú lo. Òpò tí wón ti jé omo ìdílé Olórun télè ni kò ní ju òye díè nínú ohun tí ó túmò sí láti wo Ògo Rè àti láti yípadà láti inú Ògo sínú Ògo. Òpòlopò ló rí fìrífìrí dídára ìmò Kristi, tí èyí sì mú inú won dùn. Okàn won sì ń fé ìfé Kristi tí ó jìn, tí ó sì kún ju bí wón se mò télè. Jékí okàn gbogbo fé láti fà sí Olórun.—Gospel Workers, p. 274. IIO 238.5

Sí àwon oníwàásù, onísègùn àti olùkó wa àti gbogbo àwon òsìsé ìhìnrere tó kù. Mo ní isé ìránsé fún yín. Olórun ń pè yín láti wá sí ilé tí ó ga jù láti dé òdiwòn mímó. E gbodò ní ìrírí tí ó jinlè ju èyí tí e ní tàbí e lérò wípé e lè ní. Òpò tí wón ti jé omo ìdílé Olórun télè ni kò ní òye díè nínú ohun tí ó túmò sí láti wo Ògo Rè àti láti yípadà láti inú Ògo sí inú Ògo. Òpòlopò ló rí fìrífìrí dídara mó Kristi, tí èyí sì mú inú won dùn. Okàn won sì ń fé ìfé Kristi tí ó jìn, tí ó sì kún jú bi wón se mò télè. E kò ní ìtélórùn. Sùgbón e má se jé aláìnírètí. E fi ohun tí ó dára jù ní okàn àti ìfé mímó fún Jésù. E ka gbogbo ìtànsán ìmólè sí ìsura. E máa sìké ohun gbogbo èyí tí okàn bá fé fún Olórun. E da okàn yín lékòó nínú èrò ti Èmí àti òrò mímó. E ti rí ìtànsán Ògo Rè àkókó tí ó mólè sórí ilè ayé. Bí o se ń fé tèsíwájú láti mo Olórun síi, e yóò sì mò wípé ìjáde lo Rè ni a pèsè sílè bí òwúrò. Ipa ònà òdodo dàbí ìmólè òwúrò kùtùkùtù, èyí tí ó sì ń tàn síi títí ìmólè ojó náà yóò sì fi pé. “Léhìn ìgbà tí a ti ronúpìwàdà èsè wa, tí a sì jéwó won, tí a sì ti dáríjì wá, ó ye kí a wa máa kó sí nípa Kristi, títí di ìgbà tí a yóò fi dé àbala ìmólè ń lá tí ìgbàgbó ìhìnrere tó pé.—Testimonies, vol. 8, pp. 317, 318. IIO 239.1