ISE ISIN ONIGBAGBO
Bí A Se Le Dojúko Ìdáyàfò Tàbí Àìgba-ni-níyànjú
Ó se kí àwon òjísé Olorun gbogbo mò wípé ìdáyàfò tàbí ohun èrú tó lè mú ìrèwèsì bá okàn yóò wà. Àárè yóò mú won, tí kìí se nípa ìbínú, ègàn, tàbí ìwà ìkà àwon òtá bíkòse nípa ìwà òle, dákúdájí, kògbóná-kòtutù, ìwà òtè tàbí àrekérekè àwon òré àti àwon olùrànlówó. Kódà àwon tí wón tilè nífésí àseyorí isé Olórun pàápàá yóò mú ìrèwèsì bá okàn àwon òsìsé Rè nípa gbígbó òrò ìbàjé, òrò fáàrí òhun ìyolénu àwon òtá tàbí asòdì. Láarin àwon ohun ìdáyàfoni yìí, Nehemíàh fi Olorun se ìgbékèlé rè; èyí sì ni odi ààbò wa. Ìrántí ohun tí Olorun ti se fún wa rí ni yóò jé àtìlehìn ń lá fún wa nígbà ewu. “Eni tí kò dá omo Òun tìkaararè sí sùgbón tí ó jòwó rè lówó fún gbogbo wa, yóò ha ti se tí kì yóò fún wa ní ohun gbogbo pèlú rè lófèé?” Àti wípé, “Tí Olúwa bá wà pèlú wa, tani yóò le è dojú ìjà ko wá?” Bó se wù kí Sàtánì àti àwon omo ogun re fi ète won gbé isé won kalè, Olórun lè mò, kí Ó sì so ìmò won gbogbo di asán.—Southern Watchman, April. 19, 1904. IIO 240.1
Àwon tí ó ń dúró níwájú ìjà, ń síwájú nípasè Èmí-mímó láti sisé, won a sì mò lára nígbà tí a bá mú funfun náà kúrò. Àìnírètí lè mi àwon tí ó gbiná nínú ìgbàgbó, kí ó sì da ìrèwèsì bá àwon tí ó dúró gboingboin. Sùgbón ó yé Olórun, ó sì ń kédùn béè ó nífè ẹ́ síbè. Ó ń wo èròǹgbà okàn wa láti dúró pèlú ìrójú, kí a sì gbàgbó nígbà tí ohun gbogbo sókùnkùn sí wa jé èkó tí àwon olórí nínú isé Olúwa ní láti kó. Òrun kì yóò tàsé won ní ìgbà ìsòro won. Kò sí ohun tí ó se ni láàánú, síbè tí a kò lè borí bí okàn tí ó gbékèlé Oluwa nígbàgbogbo.—Prophets and Kings, pp. 174, 175. IIO 240.2
Olorun ń pe àwon omo ogun tí kò le kùnà tàbí rèwèsì sùgbón tí ó gba isé Olúwa pèlú gbogbo ohun tí ó lè mú ni rèwèsì. Yóò jé kí gbogbo wa gba Jésù gégé bí àwòkóse.—Review and Herald, Jul 17, 1894. IIO 240.3
Àwon tí ó ń kó èkó, eni tí ó gbajúgbajà nílò láti rèwèsì tí àwon ènìyàn kò bá tétísí won tàbì gbà wón gbó, pàápàá lódò àwon tí ó pe ara won ní Krìstèénì ju ti Pọ́ọ̀lù lo àti àwon ara won tí wón jo ń sisẹ́ nínú ogbà Olúwa. Àwon òjísé àgbélébùú gbodò di ìhámóra ìsónà àti àdúra móra, kí won kó sì tèsíwájú nínú ìgbàgbó òhun ìgboyà, kí won kó má sisé ní orúko Jesu nígàbgbogbo.—The Acts of the Apostles, p. 230. IIO 240.4