ISE ISIN ONIGBAGBO
Ìyàsótò
Ìwà mímó tòótó ni fífi gbogbo ara wa jìn nínú isé Olúwa. Èyí jé ipò tí Krìstèénì gbodò gbé nítòótó. Ó ń fé okàn, èmí, ara àti agbára wa. A kò gbodò ké ara wa. Enití ó bá gbé fún ara rè nìkan kìí se Krìstèénì,-—Christ’s Object Lessons, pp. 48-49. IIO 235.3
Ohun àkókó láti kó fún àwon tí ó fé jé òsísé Olórun ni láti kú sí ara won, wón pèsè won láti ní ìwà bí ti Kristi. Èyí kìí se ohun tí ó gba nípa èkó ní àwon ilé ìwé sáyéǹsì. Èso ogbón tí o ń rí gbà láti òdò Olùko mímó ni.—The Desire of Ages, pp. 249-250. IIO 235.4
Kìí se érí tí ó múná dóko ni láti so pé Krìstèéní ni ènìyàn nítorí pé ó sàfihàn ayò púpò níti èmí ni àwon ohun síse tí ó jé àrà òtò. Ewà mímó kìí se ìgbàsókè. Ó jé jíjowú ara eni pàápàá fún ohun ti Olórun, ó jé gbígbé nípa òrò gbogbo tí ó ti enu Olórun jáde, ó jé síse ìfé Olórun, ó jé gbígbàgbó nínú Olórun nígbà ìdánwò, nínú òkùnkùn àti ìmólè, rínrìn pèlú ìgbàgbó láì wojú, gbígbékèlé Olórun pèlú èmí ìgboyà láì siyèméjì àti síninmi nínú ìfé Rè.—The Acts of the Apostles, p. 51. IIO 235.5