ISE ISIN ONIGBAGBO

232/273

Ìgboyà

A ní láti se isé tí ó níye, a gbodò gbé ìlànà ń lá kalè, ohun gbogbo lo sí gbogbo àgbáyé láti so wón jí. Àwon okuǹrin tí ìgbàgbó won kò lésè nílè, tí wọn kò sì dúró sinsin kọ́ ní yóò se isé náà nínú àkókò tí ó le koko yìí. A nílò àwon tí ó ní ìgboyà tí akoni àti ìgbàgbó àwon ajérìí ikú.—Testimonies, vol. 5, p. 187. IIO 234.6

Nínú ìgbàgbó, a gba agbára Rè, yóò se ìyípadà tí ó jìnnà, àwon tí kò ní ìrètí, àwon tí ó ní ìrèwèsì, yóò se èyí fún ìgbélékè orúko Rè. Olórun ń pe àwon olótító Rè, àwon tí ó ní ìgbàgbó nínú Rè, láti sòrò ìgboyà fún àwon tí ó ní ìgbàgbó àti ìrètí. Kí Olórun kí ó ràn wá lówó láti ran ara wa lówó àti láti gbé E ga nípa ìgbàgbó tí ó jí.—Testimonies, vol. 8, p. 12. IIO 234.7

Ìrètí àti ìgboyà wúlò púpò fún isé Olúwa. Àwon wònyí ni èso ìgbàgbó. Àìnírètí jé èsè, ó sì lòdì sí ìrònú.—Prophets and Kings, p. 164. IIO 235.1

Ìgboyà, agbára àti ìforítì jé ohun tí a gbodò ní. Bí ìdènà tí ó farahàn ní gbangba tilè dojúko ara wa, pèlú ore-òfé Rè a gbodò tèsíwájú. Dípò kí a máa gbé ìsòro wa, a pè wá láti borí won. A kò gbodò sàìnírètí ohunkóhun, kí a sì má ní ìrètí ohun gbogbo, pèlú okùn ìfé Rè tí kò légbé, Kristi ti dè wá mó ìté Rè. Èrò Rè ni pé, ipa tí ó tóbi jùlo láyé, tí ó wá láti òdo Enití ó ní gbogbo agbára yóò jé tiwa. Won á ní agbára láti kojú èmí búburú, agbára ti ayé, ikú àti iná ìléru kò lè lákóso lórí, agbára tí yóò jé kí a borí bí Kristi ti borí.—Gospel Workers, p. 39. IIO 235.2