ISE ISIN ONIGBAGBO

231/273

Ìgbàgbó

Àwon òsìsé Olórun nílò ìgbàgbó nínú Olúwa. Kò ní àìnífokànsì ìlàkàkà wa. Omo mi ise won. Ó yan àwon èmí òrun láti sisé pèlú àwon tí ń sisé Olórun. Nígbà tí a bá rò pé Olórun kò níi se gégébí Ó ti so, àti pé kò ní àkókò láti mójú tó àwon òsìsé Rè, a ta àbùkù sí Elédàá wa.—The Southern Watchman, Aug. 2, 1904. IIO 234.1

Àwon òsìsé Olórun nílò ìfé tí ó jinlè. A lè wá dáwa lékun ní ìrísí wa, sùgbón, ìmólè wa tàn léyìn wákàtí òkùnkùn. Okun àwon tí ó sin Olórun nínú ìgbà àti ìfé yóò di òtun ní ojó dé ojó.—Gospel Workers, p. 262. IIO 234.2

Ìgbàsókè, dídúró sinsin nínú ìpìlè àti ìmúdúró ohun tí à ń lépa wa nínú ìgbàgbó tí ó jìnnà, tí ìgbà tàbí ìyà kò lè mú kúrò.—Christ’s Object Lessons, p. 147. IIO 234.3

Òpòlopò ìgbà ni Krìstèénì dojúko ewu, béè isé ìsìn lè lera láti se. Èrò ìparun, ìdè tàbí ikú wà léyìn. Síbè, ohùn Olórun wípé “Tèsíwájú”. A gbodò tèlé àse yìí, bí ó tilè jé pé, ojú wa kò lè rí òkùnkùn tí ó ń be níwájú àti ìjì tí ó ń fi esè wa. IIO 234.4

Àwon ìdènà tí ó dojúko ìtèsíwájú wa kò ní pòórá níwájú okàn tí ó ń siyèméjì. Àwon tí ó ń dúró de ìgbà tí àwon ohun tí kò yé won yóò pòórá kí won tó tèlé àse Olúwa, kì yóò tèlé àse Rè rárá. Aláìní-ìgbàgbó wípé “Jé kí a dúró de ìgbà tí a yóò mú àwon ìdènà kúrò, kí a sì rí ọ̀nà a wa dáradára”. Sùgbón ìgbàgbó ń tì wá síwájú pèlú ìgboyà, ó ń fun wa ní ìrètí àti ìgbekèlé nínú ohun gbogbo.—Patriarchs and prophets, p. 290. IIO 234.5