ISE ISIN ONIGBAGBO

222/273

Jíjé Ojúlówó

Gbogbo àwon tí wón ní isé ìránsé olówò láti jé bí tiwa kò gbodò máa díbón rárá nítorí ayé ń wo omo Onírètí Bíbò Jésù tí ń sinmi ní ojó kèéje nítorí tí wón mo irú ìgbàgbó àti ìjéwó tí won ní, tí wón bá lè sèèsì rí nínú won tí kò gbé ìgbé ayé rè gégé bí ìjéwó won, won á bèrè sí ní tóka àbùkù òhun ègàn síi.—Testimonies, vol. 9, p. 23. IIO 227.4

Àwon ènìyàn le è ní ìwà tó dára àti àmúye rere, sùgbón tí wón bá bàkù níbì kan tàbí ní èsè ìkòkò, òrò won yóò dàbí imín tín-ń-tín létí àwo gbègìrì èyí tí kò sì ní bójúmu.—Testimonies, vol. 4, p. 90. IIO 227.5

Póòlù ń gbé ìgbé ayé rè pèlú àyíká òrun, gbogbo eni tí ó bá ní ìbásepò pèlú rè ni ó máa ń ní ìrírí ìbásepò Kristi nínú ayé rè. Ìgbé ayé tí Póòlù ń gbé, tí ó jé àpeere ìwà òtító tí ó ń polongo jé èyí tí ó mú kí àwon ènìyàn gbàá gbó. Níhìn-ín ni agbára òtító wà. Ìgbé ayé tí à ń gbé láì díbón jé ìwàásù ìyíni-lókàn-padà, èyí tí a fi fún àwon Onígbàgbó. Iyàn jíjà lè mú ìbínú àwon alátakò wá sùgbón àpeere ìwà-bí-Olórun ni agbára tí kò se é tako.—Gospel Workers, p. 59. IIO 227.6

Ìwà òtító kò farahàn ní ìta nìkansoso bíkòse láti inú wá ni ó ti bèrè. Tí a bá fé darí àwon elòmíràn sí ipa ònà òdodo, kódà, ìwà òdodo yìí ní láti fi ara hàn nínú ayé wa. Ìmò ogbón orí, ìjéwó ìgbàgbó kò tó bíkòse pé èmí ìfokànsìn tòótó ni ó fi òrò òtító hàn. Gbígbé ìgbé ayé rere ní ìgbà gbogbo, síso òrò mímó, ìwà àìlábùkù, èmí tí ǹ sàańú nígbà gbogbo, àpeere ìwà-bí-Olórun. Àwon ònà wònyìí ni a lè gbà tan ìmólè sí ayé.—The Desire of Ages, p. 307. IIO 228.1

Àdúrà gbígbà, ìgbani-níyànjú jé àwon ònà tí wón fi ń tan àwon ènìyàn je, sùgbón àwon èso tí ń farahàn nínú isé rere, ni bíbojú tó àwon aláìní, àwon aláìní-baba, àwon opó, ni àwon ojúlówó èso tí ń so lórí igi rere.—Testimonies, vol. 2, p. 24. IIO 228.2