ISE ISIN ONIGBAGBO

223/273

Níní Èmí Ìgboyà Láti Tèsíwájú

Olórun kìí déédé ṣe isé ìyanu láti mú kí òtító Rè tèsíwájú. Tí olùsógbà kò bá ko ilè, Olórun kò ní se isé ìyanu láti mú èrò jáde níbè. Ó máa ń sisé pèlú àgbékalè ń lá tí Ó fihàn wá. Tiwa ni láti mú kí àwon ìpinnu wònyí dàgbà kí a sì se isé èyí tí Olórun yóò jé kó ní àseyorí. Àwon tó káwó-gbera lásan tí won ń de Èmí Mímó láti mú won pèlú agídí, láti sisé yóò parun nínú òkùnkùn. Kò ye kí a kàn jòkó tetere lásán láì sisé kankan níbi isé Olórun.—The Southern Watchman, Dec. 1, 1903. IIO 228.3

Àwon kan tó ń sisé ìjèrè okàn jé aláìlágbára, enití-n ǹ-kan-kìí-pé-sú. Won kò lè dá rìn tí e kò bá tì wón. Won kò ní àmúye àwon ìwà tí ó lè dá n ǹkan se bẹ́èni won kò ní èmí àti agbára tí ń mú òyàyà wá. Àwon tí ó bá fé se àseyorí gbodò ní ìgboyà kí won sì ní ìrètí. Kìí se wípé wón ní ìwà ìlóra nìkan bíkòse kí won ó tún ní àmúye ìwà ìyára.—Gospel Workers, p. 90. IIO 228.4

Olúwa nílò irú àwon òsìsé tí won yóò mú ìségun àgbélébùú Krístì tèsíwájú.—Review and Herald, May 6, 1890. IIO 228.5

Kìí se kí a má wàásù pèlú ìlóra àti àìjáfáfá bíkòse pèlú ìtara, ìgboyà àti òrò tí a ti pinnu télè tí ó sì hàn kedere.—Testimonies, vol. 8, p. 16. IIO 229.1

A kò nílò àwon tí ń fi oge tàbí ako sòrò láti se ìwàásù yìí bíkòse kí a fi ìtara àti ìgbónára so òrò náà. A nílò àwon ènìyàn tó já fáfá, àwon ènìyàn tí won yóò fi tokàn-tara sisé pèlú agbára láti we ìjo mó àti tí won yóò sì kìlò fún ayé.—Testimonies, vol. 5, p. 187. IIO 229.2

Olorun kò fé àwon òle lénu isé Rè; bíkòse àwon òsìsé tí ó ní àròjinlè, tí wón kún fún ìfé, inú rere.—Testimonies, vol. 4, p. 411. IIO 229.3