ISE ISIN ONIGBAGBO
Àṣà Ogbón Orí
Àsà ogbón orí yìí ni àwa gégébí ènìyàn nílò láti pèsè ohun tí ìgbà fé.—Testimonies, vol. 4, p. 414. IIO 224.5
Kò ye kí a wo inú isé Olúwa láì múra sílè kí a sì rò wípé a yóò se àseyorí. Olórun ń fé àwon eniyan tó pé nínú okàn àti èrò. Jesu ń pe àwon alábàásisépò kìí se àwon arìndìn. Olórun fé àwon tí ó lè ronú jinlè tí wón sì gbón féfé láti se isé ń lá yìí tí ó lè mú ìgbàlà okàn wá.—Testimonies, vol. 4, p. 67. IIO 224.6
Àwon kan nílò láti se isé tí yóó mú okàn won dàgbà. Wón gbodò ríi dájú pé àwon ń ronú. Bí ó tilè jé wípé wón nílò elòmíràn láti gbà wón nímòràn tàbí ràn wón lówó, sùgbón tí àwon pàápàá kò bá sisé láti mú okàn won dàgbà, nígbà náà ni ìwà àìnírònú, àìláyò, àìle rántí yóò máa tèsíwájú. Olúkúlùkù ni ó gbodò setán láti kó ara rè lékòó.—Testimonies, vol. 2, p. 188. IIO 224.7
Olorun kò fé ká ní ìtélórùn pèlú òle, elérò kúkurú, a-lái-lè-kóra-eni-níjánu àti àwon tí kìí pé gbàgbé òrò.-Counsels to Parents, Teachers and Students, p. 506. IIO 224.8
Àwon ènìyàn Olórun gbodò jé eni tí ó ń kẹ́kọ̀ó gidigidi, tí ó féràn ìmò púpò, tí kìí sì fi àkókò sòfò. Nípa ìfaradà pèlú ìgbìyànjú, won le è dé ipò pàtàkì gégébí Onígbàgbó àti ènìyàn tí ó lágbára tí ó sì ni ipa.—Testimonies, vol. 4, p. 411. IIO 225.1
E je kí àkókò ó se pàtàkì. Kí a lo àkókò tí a fi ń rínrìn àjò, àkókò tí a fi ń dúró de oúnje tàbí dúró de ènìyàn láti fi máa ka ìwé tàbí se àsàrò, ó dájú wípé a ò máa rí àwon n ǹkan láti kó.—Christ’s Object Lessons, p. 343, 344. IIO 225.2
Àwon ìpinnu tí a mò ó mò se láti lo àkóko wa dáadáa yóò ràn wá lówó láti ní ìmò síi èyí tí yóò ràn wá lówó láti leè dé ipòkípò tí ó le è mú wa wúlò kí a sì ní ipa.—Christ’s Object Lessons, p. 334. IIO 225.3
Àwon ènìyaǹ tí ó bá a ní ipò elegé gbodò máa gbìyànjú láti dàgbà sókè nínú opolo lóòrèkóòrè. Won kò gbodò máa je àgbònrín èsí lóbè kí won máa so wípé èkó ìmò sáyéǹsì wà fún àwon òsìsé sáyéǹsì. Bí ó tilè jé wípé ènìyàn ni ó jé aláìlera jù nígbàtí ó wá sáyé tí ó sì jé aláìgboràn nínú ìsèdá rè, síbè ó jé enití ó ní, tí ó le è tèsíwájú. O lè máà kó sí nípa sáyéǹsì, kí o ní ìwà rere, kí o sì máa tèsíwájú nínú ogbón àti ìwà rere títí di ìgbà tí yóò fi dé abala tó pé nínú ogbón àti ìwà bí ó tilè jé wípé yóò rèhìn nínú pípé àti mímọ àwon angeli.—Testimonies, vol. 4, p. 93. IIO 225.4
Gbogbo àwon tó bá fé sisé fún Olórun gbodò tiraka láti rí dájú wípé wón pé nínú gbogbo èyà ara won àti okàn tó yè kooro. Èkó tòótó a máa múra wa sílè nípa ti ara, ogbón, àti ìwà rere láti le è se isé gbogbo, ó jé ìdánilékòó fún ara, okàn àti èmí fún isé ìsìn. Èyí ni èkó tí yóò leè dúró títí ayérayé.—Christ’s Object Lessons, p. 330. IIO 225.5
N se ni gbogbo àwon atún-okò-se, agbejórò, onísòwò, àti gbogbo òsìsé mìíràn tiraka láti le è di ènìyàn gíga tí wón jé. Ǹ jé ó wá ye kí àwon àtèlé Kristi wá rèhìn nípa ti ogbón kí won wá ya pòókì láti má mo ohun tí ó ye kí won se lénu isé ìsìn? Isé ìjèrè okaǹ ju gbogbo àwon isé ayé lo. A gbodò ní ìmò bí ènìyàn se rí àti bí okàn tí ń sisé kí a tó lèé mú àwon okaǹ to Krístì wá. A nílò èrò tó jinlè àti àdúrà gidigidi láti leè mo bí a yóò se bá àwon ènìyàn sòrò lórí òrò òtító náà.—Testimonies, vol. 4, p. 67. IIO 225.6