ISE ISIN ONIGBAGBO

184/273

Òwe Kan Tí a Múlò.

Àwọn àgbékalẹ̀ méjì tí ó wà nínú òfin Ọlọ́run ni ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ sí Ọlọ́run àti ìfẹ́ tí kò ní ìmọtara-ẹni-nìkan sí àwọn aládùúgbò wa. Àwọn òfin mẹ́rin àkọ́kọ́ àti mẹ́fà tí ó kẹ́hìn dá lórí àwọn àgbékalẹ̀ méjèèjì yìí. Kírísítì ṣe àlàyé fún adájọ́ èyí tí aládùúgbò rẹ̀ wà ní mímú òwe ọkùnrin tí ó ń rin ìrìn àjò láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Jẹ́ríkó èyí tí ó bọ́ sọ́wọ́ àwọn adigunjalè, èyí tí wọ́n jà lólè tí wọ́n sì lù tí ó sì fẹ́rẹ̀ kú tán. Àlùfáà àti ọmọ Lẹ́fì rí ọkùnrin náà níbi tí ó ti ń japoró, ṣùgbọ́n ọkàn wọn kò ṣetán láti ràn-án lọ́wọ́. Wọ́n yẹra, wọ́n sì bá ìrìnàjò wọn lọ. Nígbà tí ará Samáríà dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí ó sì rí ọkùnrin tí ó ń jẹ ìrora yìí, kò tilẹ̀ bèèrè bóyá ọmọ ìlú tàbí ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ̀ ni; ṣùgbọ́n ó tẹ̀ síwájú láti ran ọkùnrin tí ó ń kú lọ yìí lọ́wọ́ nítorí tí ó mọ̀ wí pé iṣẹ́ wà lọ́wọ́ òun láti ṣe. Ó gbé e sí orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó gbée lọ sí ilé ìwòsàn bẹ́ẹ̀ sì ni ó san owó tí ó yẹ láti fi ṣe ìtọ́jú rẹ̀. Ó sa ipá rẹ̀ láti mú ìtura báa. IIO 192.1

Arákùnrin ara Samáríà ni Kírísítì sọ wí pé ó hùwà gẹ́gẹ́ bí aládùúgbò ọkùnrin tí ó bọ́ sọ́wọ́ àwọn adigunjalè yìí. Àti Léfì àti àlùfáà yìí ni ó dúró fún àwọn ẹgbẹ́ kan nínú ìjọ, àwọn tí kò bìkítà fún àwọn tí wọ́n nílò àánú àti ìrànlọ́wọ́. Àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyìí láì ka ipò wọn sí nínú ìjọ jẹ́ arúfin. Ará Samáríà ẹ̀wẹ̀ dúró fún ẹgbẹ́ tí ó jẹ olùránnílọ́wọ́ ní tòótọ́ pẹ̀lú Kírísítì tí wọ́n sì ń tọ ipasẹ̀ Rẹ̀ nínú rere ṣíṣe. IIO 192.2

Àwọn tí ń ṣàánú fún àwọn tí nǹkan kò dán mọ́rán fún, àwọn afọ́jú, àwọn amúkun, àwọn opó, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn aláìní, àwọn tí à ń pọ́n lójú tí wọn yóò sì ní ìyè àínìpekun. Gbogbo ìwà àánú, ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tí ó kù díẹ̀ káàtó fún, àwọn afọ́jú, àwọn amúkùn, àwọn aláìsàn, àwọn opó, àwọn ọmọ orùkan ni Kírísítì kà sí wí pé a ń ṣe fún Òun, bẹ́ẹ̀ sì ni a pa wọ́n nínú ìwé àkọsílẹ̀ ní ọ̀run fún èrè. Ní ọ̀nà mìíràn, bẹ́ẹ̀ni a ó kọ àkọsílẹ̀ lòdì sí àwọn wọ̀nyìí tí kò ṣàánú gẹ́gẹ́ bí àwọn Léfì àti àlùfáà sí àwọn aláìní, kàkà bẹ́ẹ̀ tí wọ́n tún ń ṣe ohun tí kò tọ́ fún àwọn tí ó kù díẹ̀ káà tó fún wọ̀nyìí ní pa fífi ìyà kún wàhálà wọn fún èrè ti ara wọn. Gbogbo iṣẹ́ gbogbo ni Ọlọ́run yóò san ẹ̀san tí ó tọ́ sí àwọn iṣẹ́ ibi tí a ṣe sí àwọn tí a ń pọ́n lójú ní àwujọ wa.—Testimonies, vol. 3, pp. 511-513. IIO 193.1