ISE ISIN ONIGBAGBO

185/273

ORÍ KEJÌDÍNLÓGÚN ÌPÀGỌ́ JẸ́ Ọ̀NÀ ÌRÀNLỌ́WỌ́ NÍNÚ IṢẸ́

ÌGBÀGBỌ́

Ìpàdé ìpàgọ́ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ètò pàtàkì nínú iṣẹ́ wà. Ó jẹ́ ọ̀nà gbòógì tí a lè fi pe àkíyèsí ọkàn àwọn ènìyàn.-Testimonies, Vol. 6, p. 31. IIO 194.1

Nínú iṣẹ́ wọ̀yìí, a ní ìpòrúúru ọkàn nípa ọ̀nà tí a lè gbà ṣẹ́gun ẹ̀tanú àti ìwà ìbàyéjẹ́ àti ọ̀nà tí a lè gbà mú òtítọ́ tí ó ṣọ̀wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gbogbo. Ọlọ́run ti jẹ́ kí ó di mímọ fún wa wí pé ìpàdé ìpàgọ́ ni irinṣé tí a lè lò fún àṣeyọrí iṣẹ́ yìí.-Testimonies, Vol. 6, pp. 31, 32. IIO 194.2