ISE ISIN ONIGBAGBO

183/273

Àwọn Ọ̀nà Tí à Ń gbà Dán Wa Wò.

Ọlọ́run a máa dán wa wò nípasẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé yìí. Àwọn ohun kékèké ni wọ́n máa ń fi èrò ọkàn hàn. Àwọn àkíyèsí kékèké, oke aimoye ìṣẹ̀lẹ̀ kékèké àti àwọn ìwà rere ayé yìí ni wọ́n jẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ ayé yìí, àti pé gbígbàgbé àti ṣe inúrere, gba ni níyànjú, ọ̀rọ̀ ìfẹ́, àti bíbu ìyì ayé díẹ̀ ,tí ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àkópọ̀ ìwà oṣi ayé yìí jọ Yóò wá di mímọ̀ níkẹhìn wí pé sísẹ́ ara ẹni láti lè è tẹ́ elòmíràn lọ́rùn ni ó wà nínú ìwé àkọsílẹ̀ ní ọ̀run.—Testimonies, vol. 2, p. 133. IIO 191.3

Mo ri wí pé nípasẹ̀ ìpèsè-sílẹ̀ Ọlọ́run fún àwọn ẹ̀dá rẹ̀, ni àwọn opó àti àwọn ọmọ òrukàn, àwọn afọ́jú, àwọn odi, àwọn arọ àti àwon tí à ń pọ́n lójú ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn sí ìkáwọ́ àwọn Onígbàgbọ́ nípasẹ̀ ìjọ Rẹ̀, èyí sì ni ìwà òtítọ́. Àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run ń kíyèsi ìṣeṣí wa sí àwọn wọ̀nyìí tí wọ́n nílò àánú wa àti ìfẹ́ àti àwọn ìwà rere wọ̀nyìí tí kò ní ojúsàájú nínú. Ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà dán àwọn ìwà wa wò ni eléyìí. Tí a bá ní ẹ̀sìn òtítọ́ tí Bíbélì a ó ní ìmọ́lára ìfẹ́, inú rere ti ó yẹ kí a fi fún àwọn ènìyàn gbogbo nítorí Kírísítì; ó sì yẹ kí a fi ẹ̀mí ìmọre wa hàn fún ìfẹ́ Rẹ̀ tí kò lódiwọ̀n sí wa nígbà tí a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ kò tọ́ sí nípa fífi ìfẹ́ wa tí kò ní ìmọtara-ẹni-nìkan hàn sí àwọn ará àti àwọn ènìyàn tí ó kù díẹ̀ tó fún ju àwa lọ.—Testimonies, vol. 3, p. 511. IIO 191.4