ISE ISIN ONIGBAGBO

182/273

Ṣíṣe Àlejò Jẹ́ Ojúṣe Onígbàgbọ́.

Iṣẹ́ wa láyé yìí ni láti gbé ìgbé ayé tí ó ń ran elòmíràn lọ́wọ́, nípa bíbùkún elòmíràn, ṣíṣe àlejò, ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni kì í rọrùn fún wa láti ṣe ìtọ́jú àwọn tí ó nílò rẹ̀ àti àwọn ìbùkún àwùjọ àti tí àwọn ilé wa. Àwọn kan a máa yẹra láti gbé àjàgà elòmíràn. Ṣùgbọ́n àwọn elòmíràn ni yóò gbe; nítorí pé àwọn ènìyàn kò fẹ́ràn àlejò ṣíṣe tí wọn kò sì nífẹ̀ẹ́ nínú irú iṣẹ́ yìí, àwọn díẹ̀ tí ó bá ní ọkàn láti gbé àjàgà elòmíràn ni ẹrù yìí a máa wọ̀ lọ́rùn.—Testimonies, vol. 2, p. 645. IIO 191.1

“Ẹ máṣe gbàgbé láti máa ṣe àlejò nítorí ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ni àwọn elòmíràn ti ṣe àwọn ańgẹ́lí lálejò láìmọ̀”. Àwọn ọ̀rọ̀ yìí sì wúlò síbẹ̀ títí di òní. Bàbá wa ọ̀run sì tún ń pèsè ìbùkún yìí sí ọ̀nà àwọn ọmọ rẹ̀ ní ọ̀nà tó farasin, àwọn tí ó bá ṣe àwárí ìbùkún rẹ yìí máa ń ní ayọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.—Prophets and Kings, p. 132. IIO 191.2