ISE ISIN ONIGBAGBO
Nína Ọwọ́ Ìrànlọ́wọ́
Ẹ̀ṣẹ̀ ni ótóbi jùlọ nínú àwọn ìwà búburú, tiwa si ni láti ṣàánú àti láti ran àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. Kìí ṣe gbogbo ènìyàn ni a lè bá pàdé ní ọ̀nà kan náà. Àwọn kan kò gbé e sójú wí pé ebi ń pa wọ́n. A lèè ran àwọn wọ̀nyìí lọ́wọ́ nípa sísọ ọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn pẹ̀lú ìrántí rere. Àwọn kan wà tí wọ́n ṣe aláìní lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n síbẹ̀ tí wọn kò mọ̀. Wọn kò mọ irú ipò àìní tí ọkàn wọn wà. Ọpọ̀lọpọ̀ ni ó ti jìn sí ọ̀fìn ẹ̀sẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní òye nǹkan ti ọ̀run mọ́, wọ́n ti sọ ajùmọ̀ṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nù, wọn kò tilẹ̀ mọ̀ bóyá wọ́n ní ọkàn tí a lè gbàlà mọ́. Wọ́n kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tàbí ìgbàlà nínú ènìyàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wọ̀nyìí ni a lè dé ọ̀dọ̀ wọn nípa ṣíṣe àánú láìsí ojúṣàájú. A kọ́kọ́ gbọ́dọ̀ pèsè fún àìní ti ara, a gbọ́dọ̀ bọ́ wọ́n, fi aṣọ tó dára wọ̀ wọ́n. Bí wọ́n ṣe ń rí àmì ìfẹ́ tí kò lódiwọ̀n yìí, yóò rọrùn fún wọn láti ní ìgbàgbọ́ nínú ìfẹ́ Kírísítì. IIO 190.2
Ọpọ̀lọpọ̀ wọn ni ìtìjú àwọn àṣìṣe wọn ń bà lérù. Wọn a máa wo àṣìṣe wọn títí dé ìgbà tí wọn ó fi dé ipò aláìnírètí. A kò gbọdọ̀ fi ojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn wọ̀nyìí. Nígbàtí ènìyàn bá fẹ́ wẹ òkun, ìgbì omi a máa fa irú ẹni bẹ́ẹ̀ sẹ́hìn. Ẹ jẹ́ kí a nawọ́ ìrànlọ́wọ́ sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Pétérù ti na ọwọ́ ìrànlọ́wọ́ sí i nígbà tí ó ń rì sínú omi. Ẹ sọ̀rọ̀ tí ó ní ìrètí fún wọn èyí tí yóò jí ìfẹ́ dìde nínú wọn tí yóò sì fún wọn nígboyà.—Christ’s Object Lessons, p. 387. IIO 190.3
Fún àwọn ọkàn ti ẹ̀ṣẹ̀ ti sú ṣùgbọ́n tí wọn kò mọ ọ̀nà àbáyọ, ẹ fi Olùgbalà Aláàánú hàn fún wọn. Ẹ fà wọ́n lọ́wọ́, ẹ gbé wọn sókè, kí ẹ sì sọ̀rọ̀ ìgboyà àti ìrètí fún wọn. Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ọwọ́ Olùgbàlà mú.—The Ministry of Healing, p. 168. IIO 190.4