ISE ISIN ONIGBAGBO
Tí Ó Wà Fún Ìrántí.
Nínú gbogbo àwọn ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú elòmíràn, ó yẹ kí a máa rántí ìrírí tí kò dára tí àwọn elòmíràn ní. Nínú ìrántí àwọn elòḿiràn ni àwọn ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú èyí tí kò hàn sí elòmíràn. Nínú ọkàn àwọn elòmíràn ni ogun tí ó le koko pẹ̀lú ìdánwò nla wa. Àwọn elòmíràn ní ìṣòro ìdílé tí ó ń dààmú ọkàn wọn lójoójumọ́. A lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún irú àwọn ti ọkàn wọn dààmú wọ̀nyìí , nípa ṣíṣe àkíyèsí wọn, èyí tí kò ná wa ju ìgbìyànjú díẹ̀ lọ. Àwọn ènìyàn báyìí, máa sáàbà mọ rírìi ore tí a bá ṣe fún wọn, o sì máa ń jọ wọ́n lójú ju wúrà tàbí fàdákà lọ, sísọ ọ̀rọ̀ tútù sí wọn náà jẹ́ ohun tí ó dára. IIO 189.2
Àwọn kan náà wà tí wọ́n wà nínú iṣẹ́, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ bí erin ṣùgbọ́n tí wọ́n ń jẹ ìjẹ ẹ̀lírí. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ tí wọ́n ṣe aláìní ohun tó dára èyí tí ọkàn wọn ń fẹ́, irú iṣẹ̀lẹ̀ báyìí máa ń mú kí ọkàn àwọn wọ̀nyìí wúwo kí ó sì gbọgbẹ́. Àìsàn, ìrora, àìrí ìrànlọ́wọ́, ìpọ́njú yóò jùmọ̀ máa mú ìbánújẹ́ ọkàn wọn pọ̀ sí i tí a kò bá ràn wọ́n lọ́wọ́, kí a sì kẹ́dùn pẹ̀lú wọn nínú ìṣòro, ìróra ọkàn àti ìjákulẹ̀ wọn. Èyí yóò fún wa ní aǹfààní láti lè ràn wọ́n lọ́wọ́, sọ ọ̀rọ̀ ìlérí Ọlọ́run fún wọn, kí a sì jẹ́ kí wọn mọ̀ wí pé àwọn ṣì ní ìrètí.—The Ministry of Healing, p. 158. IIO 189.3
Àwọn kan wà tí ayé kò rọrùn fún, àìní wọ̀ wọ́n lọ́rùn tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ tí eléyìí kò fi àyè gba ìgbàgbọ́ nínú ọkàn wọn, wọn koọ̀ rí ìdí kankan láti dúpẹ́. Ọwọ́ ìfẹ́ tí a bà nà sí wọn nípa ọ̀rọ̀ rere, ojú àánú àti jíjẹ́ kí wọ́n mọ̀ wi pé wọ́n wúlò yóò dàbí ìgbà tí a bá fún ọkàn tí ń pòǹgbe ní omi tútù mu. Ọ̀rọ̀ àánú, ìwà rere yóò gbé àjàgà wúwo tí ó wà lórí àwọn ọkàn tí ń ṣàárè. Gbogbo àwọn iṣẹ́ rere wọ̀nyìí ni ọ̀nà tí à ń gbà fi iṣẹ́ Kírísítì hàn fún ìran ènìyàn.—Thoughts From the Mount of Blessing, p. 23. IIO 190.1