ISE ISIN ONIGBAGBO
Ìtẹ́wọ́gbà Náà.
Àwọn ọmolẹ́yìn Kírísítì gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́, gẹ́gẹ́ bí Òun náà ti ṣe é. A gbọ́dọ̀ fún àwọn tí ebi ń pa lóúnjẹ, daṣọ bo àwọn tí wọ́n wà níhòhò, kí a sì tu àwọn tí ń ṣíṣẹ̀ẹ́ tí a sì ń pọ́n lójú nínú. Ó yẹ kí á wàásù fún àwọn tí wọ́n ti sọ ìrètí nù kí á sì fi dá wọn lójú wípé wọ́n ṣì ní ìrètí, àti wí pé a o mú ìlerí tí Ọlọ́run ti ṣe fún wa ṣe, “Òdodo rẹ̀ yóò máa wà níwájú wa àti ògo Ọlọ́run yóò sì máa tọ̀ wá lẹ́hìn.—The Desire of Ages, p. 350. IIO 186.2
Àwọn tí wọ́n ti ń ṣe ìrànlọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Onígbàgbọ́ yìí ti ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ láti ṣe, Ó sì ti tẹ́wọ́gba iṣẹ́ wọn. Èyí tí wọ́n ti ṣe ní ìlànà yìí ni iṣẹ́ tí gbogbo ọmọ Ìjọ Onírètí gbọ́dọ̀ fi tọkàn-tọkàn tẹ́wọ́gbà kí wọ́n sì dìímú ṣinṣin. Ní kíkọ ojúṣe wa, èyí tí ó wà ní ìkáwọ́ wa yìí, ní kíkọ̀ láti ní àjàgà yìí, ń ṣe ni ìjọ ń pàdánù lọ́pọ̀lọpọ̀. Ìbá ṣe pé ìjọ mu iṣẹ́ yìí lọ́kùn-ún-kún-dùn ni, wọn ì bá jẹ́ ọ̀nà láti gba ọ̀pọ̀ ẹ̀mí là.—Testimonies, vol. 6, p. 295. IIO 187.1
Gbogbo ẹ̀bùn Ọlọ́run ni a gbọ́dọ̀ lò láti fi bùkún àwọn ìran ènìyàn gbogbo láti mú ìtura bá àwọn tí ó ṣe aláìní. A gbọ́dọ̀ bọ́ àwọn tí ebi ń pa, da aṣọ bo àwọn tí ó wà níhòòhò, tọ́jú àwọn opó àti àwon ọmọ òrukàn, láti wàásù fún àwọn oníròbínújẹ́ àti àwọn tí a pọ́n lójú. Ọlọ́run kò fẹ́ kí òṣì kí ó gbinlẹ̀ nínú ayé. Ọlọ́run kò fẹ́ ìwà bámúbámú ni mo yó èmi ò mọ̀ bóyá ebí ń pa ẹnìkankan. Nígbà ti awon elòmíran kò sì rí nǹkan jẹ. Àwọn ohun amáyé gbádùn ni Ó ti fi sí ìkáwọ́ àwọn ènìyàn gbogbo láti lè máa ṣe rere nípa bíbùkún ọmọ ènìyàn. Olúwa sọ wí pé, “Ta ohun ìní rẹ kí o sì fi ṣe ìtọrẹ fún àwọn ẹlòmíràn”. Ẹ ṣetán láti ṣe alábàápín kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ láti polongo ìhìnrere. “Nígbà tí ẹ bá pe àsè, ẹ pe àwọn aláiìní, àwọn arọ, àwọn afọ́jú”. “Ẹ tú àwọn ẹni ibi ká”, “Ẹ gbé àjàgà kúrò lọ́rùn àwọ́n ènìyàn”, “Ẹ tú àwọn oǹdè sílẹ̀”, “Ẹ já gbogbo àwọn àjàgà”, Ẹ fi oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń pa”, “Ẹ mú àwọn ọkàn tí a tanù wá sílé yín”, “Nígbà tí ẹ bá rí àwọn tí ó wà níhòòhò, ẹ daṣo bò wọ́n”, “Ẹ tu àwọn tí a ń pọn lójú nínú”, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ sì wàásù ìhìnrere fún gbogbo ẹ̀dá”. Àwọn wọ̀nyìí ni àṣẹ Olúwa. Ǹ jẹ́ àwọn tí a ń pè ní Onígbàgbọ́ ń ṣe àwọn iṣẹ́ wọ̀nyìí bí?.—Christ’s Object Lessons, pp. 370, 371. IIO 187.2
Iṣé rere ni èso tí Kírísítì ń fẹ́ kí á so, ọ̀rọ̀ rere, iṣẹ́ àánú, ṣiṣẹ́ àwọn aláìní, àwọn ọtọ̀ṣì, àti àwọn tí à ń pọ́n lójú jẹ̀jẹ́. Nígbà tí a bá káànú àwọn ọkàn tí ó wúwo tàbi ṣòfò, nígbà tí a bá ń fi fún àwọn aláìní, tí a fi aṣọ bo àwọn tí ó wà níhòòhò, tí a ń ṣe ìtọ́jú àwọn àlejò nígbà náà ni àwọn ańgẹ́lì yóò súnmọ́ ọ̀dọ̀ wa tí Olúwa yóò sì mú ìrora wa kúrò. Gbogbo àwọn ìwà rere tí à ń hù ni ó ń mú kí ayọ̀ ó wà lọ́rùn- un. Láti ọ̀run wá ni Ọlọ́run ti bojúwò àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ àánú wọ̀nyìí tí Ó sì kà wọ́n mọ́ ìṣura iyebíye Rẹ̀, “Wọ́n ó sì jẹ́ t’Emi ní ọjọ́ tí Mo bá ka àwọn ìṣura Mi”. Gbogbo iṣẹ àánú sí àwọn aláìní àti àwọn tí ìyà ń je ni ó dàbí ẹni wí pé Jésù ni à ń ṣee fún. Nígbà tí a bá ran àwọn tálákà lọ́wọ́, tí a bá àwọn tí à ń pọ́n lójú kẹ́dùn, tí a sì bá àwọn ọmọ òrukàn ṣeré nígbà náà ni à ń ní ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ pẹ̀lú Jésù.—Testimonies, vol. 2, p. 25. IIO 187.3
Ṣíṣe àkójọ àwọn aláìní, àwọn tí a pọ́n lójú, àwọn ti ń jẹ̀yà, àwọn ni iṣẹ́ tí gbogbo ìjọ tí ó bá gba òtítọ́ ti àkókò yìí gbọ́ yẹ kí ó ti máa ṣe. Ó yẹ kí á fi àáánú hàn bí i ti ará Samáríà ni nípa pípèsè àwọn ohun èlò ti ara, bíbọ́ àwọn tí ebi ń pa, mímú àwọn òtòṣì tí ebi ń pa wá sínú ilé wá nípa gbígbà ore-ọ̀fẹ́ àti okun lójoójúmọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí inú wọn kò dùn. Kí a sì ran àwọn tí kò lè ran ara wọn lọ́wọ́. Nípa ṣíṣe iṣẹ́ yìí, a ní aǹfààní tí ó dára láti fi Kírísítì tí a kàn mọ́ àgbélèbú hàn.—Testimonies, vol. 6, p. 276. IIO 188.1
Ọ̀pọ̀ ni ó ń yà lẹ́nu ìdí tí àdúrà wọn kò fi ní ìtumọ̀, tí ìgbàgbọ́ wọn fúyẹ́ tí kò lẹ́sẹ̀ ń lẹ̀, ìrìnàjò ìgbàgbọ́ wọn ṣ’ókùnkùn kò sì ṣe ń gbẹ́kẹ̀lé. Wọn a wí pé àwọn ṣáà ti gba àwẹ̀, “tí a sì ti rìn pẹ̀lú ìbànújẹ́ ọkàn níwájú Olúwa àwọn ọmọ ogun?” Nínú Isaiah orí kejìdínlọ́gọ́ta Jésù fihàn wá níbẹ̀ bí ìṣípòpadà yóò ṣe bá àwọn ìwà wọ̀nyìí. . . .ẹsẹ̀ kẹfà àti ìkeje. Èyí ní ọ̀nà tí Kírísítì ti là sílẹ̀ fún àwọn tí ọkàn wọn ń ṣàárẹ̀, àwọn oníyèméjì ọkàn, àwọn ti ọkan wọn n pòrùúru. Ẹ jẹ́ kí eni tí ó ti fi ìgbà kan rìn níwájú Olúwa pẹ̀lú ìbánújẹ́ ọkàn, dìde kí ó sì ran ẹni tí ó nílò ìrànlọ́wọ́ lọ́wọ́.—Testimonies, vol. 6, p. 266. IIO 188.2
Ògo Olúwa máa ń wà nínú gbígbé ẹni tó ti ṣubú dúró, títu oníròbínújẹ́ nínú. Nígbà tí kírísìtí bá ti ń jọba nínú ọkàn ènìyàn, Yóò ṣàfihàn rẹ̀ lọ́nà kan. Ibikíbi tí ó bá ti ṣe iṣẹ́, ìsìn Rẹ̀ yóò máa bùkún àwọn ènìyàn, níbikíbi tí ó bá ti ṣiṣẹ́, ìmọ́lẹ̀ a máa wà.—Christ’s Object Lessons, p. 386. IIO 188.3
Opó Sáréfátì fi oúnjẹ rẹ̀ ṣe ìtọ̀rẹ àánú fún Èlíjàh, lẹ́hìn-ò-rẹhìn, a dá ẹ̀mí rẹ̀ àti ti ọmọ rẹ̀ sí. Bẹ́ẹ̀ náà ni yóò sì rí fún gbogbo ẹni tí ó bá ṣàánú àwọn aláìní. Ọlọ́run ti ṣèlérí ìbúkún ńlá. Bẹ́ẹ̀ni kò tíì yípadà. Agbára Rẹ̀ sì wà síbẹ̀ àní bí ó ti rí ní ìgbà Èlíjàh.—Prophets and Kings, pp. 131, 132. IIO 188.4
Ìfẹ́ Kírísítì tí ó bá fi ara hàn nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí kò mọ tìwọ̀n ara rẹ̀ nìkan máa ń yí ọkàn àwọn ènìyàn búburú padà ju ìdájọ́ ti inú ilé ìdájọ́ lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ilé ìdájọ́ máa ń fi ìyà jẹ àwọn arúfin, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ọkàn àwọn ajíhìnrere léè ṣe jù báyìí lọ. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ọkàn tó yigbi lábẹ́ òfin máa ń yòrò lábẹ́ ìfẹ́ Kírísítì.—The Ministry of Healing, p. 106. IIO 189.1