ISE ISIN ONIGBAGBO
Ogbón
Gbogbo àwon tó jòwó ayé won fún Olórun yóò fi gbogbo èrò won, àdúrà won, ìtara won papò pèlú ogbón sínú ise won.—Signs of the Times, May 29, 1893. IIO 230.6
Tí ènìyàn bá ní ogbón, òyàyà àti bí a se le se n ǹkan, yóò se àseyorí nínú àwon okòòwò rè àti tí a bá fi irú ìwà yìí sínú ohun tíí se ti Olórun, a yóò rí àbáyorí rè ní ìlópo méjì, nítorí a yóò pa agbára Olórun pò mó ti ènìyàn.—Testimonies, vol. 5, p. 276. IIO 231.1
A nílò òpòlopò ogbón àti ìmò láti se isé ìjèrè okàn. Olùgbàlà wa kò fi ìgbà kan pa òtító lénu mó bíkòse pé kí Ó so ó jáde pèlú ìfé. Nínú ìbásepò Rè pèlú àwon ènìyàn, Ó máa ń lo òpò ogbón, Ó ń se inú rere béè sì ni Ó ní èmí àròjinlè. Kò fìgbà kan síwàhù sí enikéni, kò sòrò tó korò sí ènìyàn láìnídìí, k’Ò se ohun tó lè mú ìrora bá àwon tí ó lẹ̀ mo lára. Kò bá àìlera àwon eniyan wí. Láìfòyà ni ó bá àwon alágàbàgebè, aláìgbàgbó, àti àwon elésè wí sùgbón pèlú omijé tí ó hàn nínú òrò Rè ni Ó fi ń so àwon òrò líle náà sí won. Kò ba òtító jé, sùgbón Ó ń fi ìwà jéjé bá ìran ènìyàn lò. Gbogbo okàn ni ó se iyebíye ní ojú Rè. Ó fi ìyìn òrun wo ara Rè, sùgbón síbè, Ó teríba pèlú ìkáánú fún gbogbo àwon omo ìdílé Olórun. Gbogbo ènìyàn ni Ó rí gégé bí eni tí ó jé isé Rè láti gbàlà.—Gospel Workerss, p. 117. IIO 231.2
Àwon kan wà tí ó jé oníwàdùwàdù èdá, sùgbón síbè tí wón jé olódodo, léhìn ìgbà tí a bá ti sàlàyé òrò òtító náà fún won, yóò bá àwon tí won kò wá pèlú wọn sòrò lójijì tàbí láìròtélè, won yóò sì jé kí won fà séhìn nínú òtító, èyí tí àwa ń fé kí won mò. “Àwon omo ayé yìí nínú ìran won gbón ju àwon omo ìmólè lo”. Àwon onísòwò àti àwon olósèlú ayé mo bí a se ń kó nípa bí a se ń bu olá fún ènìyàn nítorí ó jé ìlànà mímú okoòwò won rewà, kí ó sì dùn-ún wò lójú. Wón ń se eléyìí kí won baà lè ní ipa lórí okàn àwon tó yí won ká, Olórun pàápàá yóò tì wón léhìn.—Testimonies, vol. 3, p. 68. IIO 231.3
A gbodò tan ìhìnrere náà ká, sùgbón a gbodò ní àkíyèsára láti má se àsejù àti bu enu àté lu àwon tó wà nínú òkùnkùn tàbí tí kò ní iná tí a ní. A kò gbodò torí ìmò tí a ní kí a má fi ìwòntùnwonsì bá àwon omo Ìjo Àgùdà sòrò ònà ìyè. Nínú àwon omo Ìjo Àgùdà, òpòlopò won ló ń se déédé nínú èsìn nípa òye tí wón ní àti ìná ìhìnrere tó tàn sí won, Olórun á se isé nípa ti won.—Testimonies, vol. 9, p. 243. IIO 231.4