ISE ISIN ONIGBAGBO

218/273

ÈKÓ KẸRÌNLÉLÓGÚN AYỌ ÀMÚYẸ FÚN ÀṢEYORÍ IṢÉ ÌSÌN ONÍGBÀGBỌ́

Agbára Láti Sisé

Àìbìkíà àti àìlágbára fún isé jé ohun àìbòwò fún Olorun. Nígbàtí a bá mò wípé à ń sisé fún Olorun, a yóò ní ìtara púpò sí ohun tí íse ti èmí ju ti télè lo. Níní ìmò yìí ni yóò jé kí a tají, kí a ní ìtara àti àkíyèsí pèlú agbára ìfaradà láti se gbogbo isé.-Testimonies, Vol. 9, p. 150. IIO 223.1

Àkókò yìí kò gba fífi òle sisé bíkòse kí a fi agbára sisé pèlú ìyara-eni-sótò tó jinlè. Háà, òrò yìí wò mí lára tóbéè gé tí mo fi kígbe sí Olórun wípé “Dìde kí O sì rán àwon òsìsé tí ó mo ojúse won, àwon tí wón ti kan ìwà èsè àti ìbòrìsà mó àgbélébùú.-” Testimonies, Vol. 9, p. 27. IIO 223.2

Isé tí a gbé lé àwon omo èhìn lówó jé isé tí wón gbodò fi gbogbo agbára se nítorí èsù ń lo gbogbo agbára rè láti gbógun tì wón.-The Act of Apostle, p. 31. IIO 223.3