ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

1/42

ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

ORI KINI—ÌPARUN JÉRÚSÁLẸMÙ

“Ì bá ṣe pé ìwọ mọ, loni yii, ani ìwọ, ohun ti i ṣe ti alaafia rẹ! Ṣugbọn nisinsinyi, wọn pamọ kúro ni ojú rẹ. Nítori ọjọ n bọ fun ọ, tí awọn ọtá rẹ yoo wa yàrà ka ọ, wọn o si yí ọ ka, wọn o si ká ọ mọ ni ìhà gbogbo. Wọn o si wó ọ palẹ, àti àwọn ọmọ inú rẹ; wọn ki yoo si fi okuta kan sílẹ lori ara wọn; nítori ti ìwọ ko mọ ọjọ ibẹwo rẹ.” Luku 19:42—44. ANN 5.1

Jesu wo Jerusalẹmu lati ori-oke Olifi. Aworan ti o wà niwaju Rẹ dara, ó si tutu. Ó jẹ àkókò àjọ Ìrékọjá, lati gbogbo ilẹ̀ ayé awọn ọmọ Jakọbu pejọ pọ sibẹ lati ṣe àjọyọ àjọdún nla orile ede wọn yii. Laarin àwọn ọgbà àti ọgbà àjàrà, ati lóri àwọn pápá oko tútu tí àwọn arìnrìnàjò pa àgọ wọn sí, a rí àwọn òkè kékèkẽ, àwọn aafin nla, àti àwọn ògiri aabo nla nla tí wọn nípọn ti Olú Ilu Israeli. Ọmọbìrin Síoni n rò nínú ìgbéraga rẹ lati sọ wípé, Mo jóko bí ọbabinrin, èmi kì yóò sì rí ìbànújé; Ó rẹwà nígbà náa ó sì rò wípé òun ní ààbò nínú ojú rere Ọrun bíi ti ìgbà ìsáaju nígbà tí ọba akọrin náa kọrin wípe: “Dídára ní ipò ìtẹdó, ayọ gbogbo ayé ni òkè Sioni . . . ìlú Ọba nlá.” O. Dafidi 48:2. Ní ojútáyé ni ilé tẹmpili tó rẹwà náa wà. Ìtànsán oòrùn tí n wọ tàn sí ògiri olokuta iyebiye tí ó funfun bi yìnyín, ó tan ìmọlẹ padà lati enu ilẹkùn oníwúrà, àti ilé ìṣọ, àti ṣónṣo tẹmpili. “Ohun tí ó pé ní ẹwà,” ó dúró, ohun àmúyangàn orílẹ èdè Ju. Èwo nínú àwọn ọmọ Israeli ni yóo bojú wo àwòrán yìí tí kì yóò kún fún ayọ àti ìyàlẹnu! Ṣùgbọn èrò míràn tí ó jìnnà réré ni ó kún ọkàn Jesu. “Nígbà tí Ó si súnmọ itòsí, Ó ṣíjú wo ìlú náà, Ó sì sọkún le lórí.” Luku 19:41. Láarín àjọyọ ìwọlé pẹlú ìṣẹ́gun, nígbà tí a sì ń ju imọ ọ̀pẹ, tí hòsanna ń ró padà láti orí àwọn òkè, tí ọpọ ohun ń pè É ní ọba, ń ṣe ni ìbànújẹ tí a kò lè ṣàlàyé bo Olùràpadà aráyé lójiji. Òun Ọmọ Ọlọrun, Ẹni ìlérí Israeli, tí agbára Rẹ ti ṣẹgun ikú tí ó sì ti pe àwọn òndè Rẹ kúrò ní ipò òkú, ń sọkún, kì í ṣe ti ẹdùn ọkàn lásán, ṣùgbọn ti ìrora tí ó lágbára tí kò lè pamọra. ANN 5.2

Kò sọkún fún ara Rẹ, bí ó tilẹ jẹ wípé Ó mọ ibi tí ẹsẹ Òun ń lọ. Níwájú Rẹ ni Getsemani wà níbi tí yoo ti jẹ ìrora ọkàn. Ẹnu ọnà—àgùntàn wà lẹbá ibẹ, nibi tí a máa n mú ẹran ìrúbọ gbà kọjá fún ọpọlọpọ ọdun, tí a o sì ṣí sílẹ fun nígbà tí a o “mu wá gẹgẹ bí àgùntàn tí a mú wá síwájú ẹni tí yóò pá.” Aisaya 53:7. Ní itòsí ni Kalfari wa, ibi tí a ti ń kanni mọ àgbélèbú. Ní ojú ọnà tí Kristi yóò rìn láìpẹ ni ìbẹ̀rù òkùnkùn ńlá yóò wà, bí Ó ti ń fi ọkàn Rẹ ṣe ètùtù fún ẹṣẹ. Síbẹ kì í ṣe ìrònú ìrora tí ó ju ti èniyan lọ tí yóò jẹ ni ó da ìkuuku bo ẹmí tí kò ní ìmọ ti ara ẹni nìkan náà. Ó sọkún fún ọgọọrọ àwọn eniyan tí ìparun yóò dé bá ní Jerusalẹmu—nítorí ìfọjú àti àìnírònúpìwàdà àwọn tí Ó wá láti bùkún fún àti láti gbàlà. ANN 5.3

Ìtàn ìkẹ àti ìdáabòbò pàtàkì tí Ọlọrun fihàn fún àwọn eniyan Rẹ tí Ó yàn fún ọpọlọpọ ọdún ni ó ṣípayá síwájú Jesu. Níbẹ ni òkè Moria gbé wà, níbi tí ọmọ ìlérí tí a fẹ fi rúbọ tí kò sì janpata, tí a dè e mọ orí pẹpẹ—àpẹẹrẹ ìrúbọ Ọmọ Ọlọrun. Níbẹ ni a ti fi ìdí ìbùnkún májẹmú, ìlérí tí ó logo ti Mesaya múlẹ fún baba ìgbàgbọ. Jenesis 22:9, 16—18. Níbẹ ni iná ẹbọ tí ń gòkè lọ sí ọrun lati orí ilẹ ìpákà Ornani ti yí idà angẹli apanirun padà (1 Kronika 21)—àpeere tí ó tó fún ẹbọ àti ìbálàjà Olugbala fún eniyan ẹlẹṣẹ. Ọlọrun bu iyì fún Jerusalẹmu ju ohunkóhun lọ lórí ilẹ ayé. Ọlọrun ti “yan Jerusalẹmu,” “Ó ti fẹ fún ibùgbé Rẹ.” O. Dafidi 132:13. Nibẹ fún ọpọlọpọ ọdún, ni àwọn woli mímọ ti ṣe iṣẹ ìránṣẹ ìkìlọ wọn. Níbẹ ni àwọn alufa ti fi àwo tùràrí, tí ìkuuku òórùn tùràrí, pẹlú àdúrà àwọn olùjọsìn gòkè lọ síwájú Ọlọrun. Nibẹ ní ojoojúmọ ni a ti ń fi ẹjẹ ọdọ àgùntàn tí a pa rúbọ, èyí tí ó ń tọka sí Ọdọ Aguntan Ọlọrun. Nibẹ ni Jehofa ti fi ara Rẹ hàn lórí ìtẹ àánú. Níbẹ ni àkàsọ tí ó yanilẹnu nì dúró sí, èyí tí ó so ayé pọ mọ ọrun (Jẹnẹsis 28:12; Johannu 1:51)—àkàsọ lórí èyí tí àwọn angẹli Ọlọrun ń gòkè tí wọn sì ń sọkalẹ, tí ó ṣí ọnà sí ibi mímọ jùlọ sílẹ fún aráyé. Bí ó bá jẹ wípé Israeli gẹgẹ bí orílẹ èdè ṣe ìgbọran sí Ọlọrun ni, Jerusalẹmu ì bá dúró títí láe gẹgẹ bí àyànfẹ Ọlọrun. Jeremaya 17:21—25. Ṣugbọn ìtàn àwọn eniyan tí a bùkún fún yìí ṣe àfihàn ìfàsẹyin àti ìṣọtẹ. Wọn ṣe àtakò oore ọfẹ Ọrun, wọn ṣi anfani wọn lò, wọn gan anfani wọn. ANN 5.4

Bí ó tilẹ jẹ wípé Israeli ti fi “àwọn òjíṣẹ Ọlọrun ṣe ẹlẹya, wọn kẹgàn ọrọ Rẹ, tí wọn sì fi àwọn woli Rẹ ṣẹsin” (2 Kronika 36:16), Ó sì fi ara Rẹ hàn fún wọn gẹgẹ bí “Oluwa Ọlọrun, alaanu, oloore ọfẹ, onípamọra tí Ó pọ ní oore àti òtítọ” (Eksodu 34:6); láìka ìkọsílẹ wọn látìgbàdégbà sí, àánú Rẹ sì ń tẹsíwájú pẹlú ìpẹ rẹ. Pẹlú ìkaanú ìfẹ tí ó ju ti baba sí ọmọ tí ó ń tọjú lọ, Ọlọrun “rán àwọn òjíṣẹ Rẹ sí wọn, Ó ń dìde ní kùtùkùtù, Ó ṣì ń ránṣẹ, nítori tí Ó ní ìyọnú sí àwọn eniyan Rẹ àti sí ibùgbé Rẹ” 2 Kronika 36:15. Nígbàtí ìbáwí, ípẹ, ati ìkìlọ kùnà, Ó rán ẹbùn ọrun tí ó dára jùlọ sí wọn; àní Ó tú gbogbo ọrun sílẹ nínú ẹbùn kan ṣoṣo náà. ANN 6.1

Ọmọ Ọlọrun fúnra Rẹ ni a rán láti pàrọwà sí ìlú tí kò ronúpìwàdà yìí. Kristi ni Ó mú Israeli jáde láti Ijipti wa gẹgẹ bí èso àjàrà tí ó dára. O. Dafidi 80:8. Owó ara Rẹ ni Ó fa àwọn alaigbagbọ tu kúrò níwájú rẹ. Ó gbìn wọn sí “orí òkè tí ó lọrá.” Ìkẹ ìdaabòbò Rẹ ni Ó fi yi ká. Àwọn ìránṣẹ Rẹ ni Ó rán láti máa tọjú rẹ. Ó sọ wípé “Kíló tún yẹ kí n ṣe fún ọgbà àjàrà Mi tí Èmi kòì tí ì ṣe si?” Aisaya 5:1—4. Bí ó tilẹ jẹ wípé nígbà tí Ó wò wipe o ye ki o mu eso wa, èso kikan ni o mu wá, sibẹ pẹlu ireti wipe yoo so eso, Ó funra Rẹ wa sinu ọgba àjara Rẹ boya o le gba a sile kuro ninu iparun. O gbẹ ilẹ yi àjara Rẹ ka; O wọn ọwọ rẹ, O si fẹran rẹ. Agara ko da A ninu akitiyan Rẹ lati ra ajara ti O funra Rẹ gbin yii padà. ANN 6.2

Fun ọdun mẹta Oluwa imọlẹ ati ogo n lọ O si n bo laarin awọn eniyan Rẹ. O “rin káàkiri O si n ṣ‘oore, O n wo gbogbo awọn ti eṣu n jẹniya san,” O n ṣe iwosan fun awọn onirobinujẹ ọkan, O n tu awọn ti wọn wà ninu igbekun silẹ, O n la oju awọn afọju, O n mu arọ rin, ati ki odi o gbọran, O n sọ adẹtẹ di mimọ, O n ji oku dide, O si n waasu iyinrere fun awọn otosi. Ise 10:38; Luku 4:18; Matiu 11:5. Gbogbo eniyan ni a kede ipe oore ofe yii fun: “Ewa si ọdọ Mi, gbogbo ẹyin ti n ṣiṣẹ, ti a si di ẹru wuwo le lori, Emi o si fi isinmi fun yin.” Matiu 11:28. ANN 6.3

Bi o tile je wipe a fi ibi san oore fun, ti a si fi ikorira san ifẹ Rẹ pada (O. Dafidi 109:5), O ṣe iṣẹ aanu Rẹ laikaarẹ. Ko si ẹni ti o wa aanu Rẹ ti O ta danu. Alarinkiri ti ko nile, ẹgan ati aini ni ipin Rẹ lojoojumọ, O gbe lati ṣe iranṣẹ fun aini awọn eniyan, ki O si mu ki ibanujẹ wọn o dinku, lati rọ wọn lati gba ẹbun iye. Ìgbi aanu ti awọn ọlọkan lile yii da pada pada wa pẹlu igbi ti o lagbara si ti o kun fun ikaanu, ati ifẹ ti a ko le fẹnu sọ. Ṣugbọn Israeli ti yi pada kuro lọdọ ọrẹ timọtimọ rẹ ati Ẹnikan soso ti O le ran an lọwọ. A gan ipe ifẹ Rẹ, a kọ imọran Rẹ silẹ, a si fi ibawi Rẹ ṣẹsin. ANN 6.4

Wakati ireti ati idariji n sare kọja lọ; ago irunu Ọlọrun ti a fa sẹyin fun igba pipẹ ti fẹrẹ kun. Ìkuuku ti o n ko ara jọ pọ lati igba ifasẹyin ati iṣọtẹ ti o wa dudu ni akoko yii fun ijiya, ni o fẹ jabọ sori awọn eniyan ẹlẹṣẹ; Ẹni ti o si jẹ wipe Oun nikan ni O le gba wọn lọwọ idajọ ti o ku si dẹdẹ ni wọn ti gan, ti wọn kọ silẹ, ti o si ku diẹ fun wọn lati kan An mọ agbelebu. Nigba ti a ba gbe Kristi ko si ori agbelebu ni Kalfari, akoko Israeli gẹgẹ bi orilẹ ede ti Olorun ṣaanu fun, ti O si bukun fun yoo dopin. Adanu ọkan kan ṣoṣo jẹ ajalu ti o tobi ju gbogbo ere ati iṣura aye yii lọ bi a ba fi wọn we ara wọn; ṣugbọn bi Kristi ti wo Jerusalẹmu, iparun odindi ilu nla, ti gbogbo orilẹ ede, naa wa niwaju Rẹ—ilu naa, orilẹ ede naa, ti o ti fi igba kan jẹ ayanfẹ Ọlọrun, iṣura aṣayan Rẹ. ANN 6.5

Awọn woli ti sọkun lori ifasẹyin Israeli ati iparun nla ti a o fi bẹ ẹṣẹ wọn wo. Jeremaya fẹ ki oju oun jẹ orisun oje, ki oun baa le sọkun lọsan ati loru nitori iparun ọdọmọbinrin awọn eniyan rẹ, nitori ti a ko agbo Oluwa lọ ni igbekun. Jeremaya 9:1; 13:17. Bawo ni ẹdun ọkan Rẹ a ti pọ to, Ẹni ti oju iwoye Rẹ wo ohun ti yoo ṣẹlẹ, ki i ṣe fun odun diẹ, ṣugbọn fun ọdun pipẹ! O wo angeli apanirun ti o gbe ida soke sori ilu ti o fi igba pipẹ jẹ ibugbe Jehofa. Lati ori oke Olifi, ni ibudo gan ti Titu ati awọn ọmọ ogun rẹ tẹdo si, O wo kọja afonifoji, awọn gbọngan ati ogiri mímọ, pẹlu oju ti o kun fun omije, o ri ni ọna ti o banilẹru, awọn ogiri ti awọn ẹgbẹgun ọta yipo. O gbọ iro ẹsẹ awọn ọmọ ogun ti n tò lọwọ̄wọ lọ si oju ogun. O gbọ ohùn awọn iya ati ọmọ bi wọn ti n kigbe fun ounjẹ ninu ilu ti a kamọ. O ri ti a n fi ina jo awọn ile mimọ rẹ ti wọn lẹwa, ati awọn aafin ati ile iṣọ rẹ, ti ibi ti wọn wa ni igbakan ri di ahoro. ANN 6.6

O fi oju inu wo o, O ri bi a ti fọn awọn eniyan majẹmu kaakiri si gbogbo orilẹ ede “bi ọkọ ti o bajẹ ninu aṣalẹ.” Ninu idajọ ti aye yii, eyi ti o fẹ bọ lu awọn ọmọ rẹ, O ri ìdọgin akọkọ lati inu ago ibinu eyi ti yoo mu tan patapata ni akoko idajọ ikẹyin. Ikaanu Ọlọrun ati ifẹ tí ó ní ìyọnú ni o jade ninu awọn ọrọ ti o banininuje yii: “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, iwọ ti o ti pa awọn woli, ti o sì sọ awọn ti a rán si ọ ni okuta, igba melo ni Emi yoo ko awọn ọmọ rẹ jọ pọ, bi adiyẹ ti n radọ bo awọn ọmọ rẹ labẹ iyẹ rẹ, ṣugbọn iwọ kò jẹ.” I ba ṣe wipe iwọ ti a ṣaanu fun ju gbogbo orilẹ ede lọ, mọ igba ibẹwo rẹ, ati awọn ohun ti wọn jẹ mọ alaafia rẹ! Mo ti dawọ angẹli idajọ duro, Mo ti pe ọ wa si ironupiwada, ṣugbọn pabo ni wọn jasi. Ki i tilẹ n ṣe iranṣẹ, aṣoju tabi awọn woli ni iwọ kọ silẹ tí o sì ṣátì, ṣugbọn Ẹni Mimọ Israeli, Olurapada rẹ. Bi a bá pa ọ run iwọ ni o fa a o. “Ẹyin ko ni wa si ọdọ Mi ki ẹ baa le ni iye.” Matiu 23:37; Johannu 5:40. ANN 7.1

Kristi ri apẹẹrẹ araye ti o ti yigbì ninu aigbagbọ ati iṣọtẹ, ti o n sare lọ pade idajọ ẹsan Ọlọrun ninu Jerusalẹmu. Iparun ìran ti o subu ti o wọ Ọ lọkan ni o mu ẹkun kíkoro jade lati ètè Rẹ wa. O ri akọsilẹ ẹṣẹ ti a to lẹsẹẹsẹ ninu oṣi, ẹkun ati ẹjẹ eniyan. Ọkan Rẹ kun fun ikaanu ainipẹkun fun awọn ti a n pọn loju ti a si n jẹ niya ninu aye; O fẹ lati tu gbogbo wọn lara. Ṣugbọn ọwọ Rẹ ko le yi igbi ibanujẹ wọn pada; ìwọnba awọn pérete ni yoo wa Orisun kan ṣoṣo wọn fun iranlọwọ. O ṣetan lati fi ọkan Rẹ lelẹ de oju iku, lati mu igbala wa si arọwọto wọn; ṣugbọn awọn diẹ ni yoo wa si ọdọ Rẹ ki wọn baa le ri iye. ANN 7.2

Ọba ọrun n sọkun! Ọmọ Ọlọrun ayeraye n damu ninu ẹmi, irora ọkan tẹ ori Rẹ ba! Iṣẹlẹ yii jẹ iyalẹnu fun Ọrun. Aworan ti a ri nibi yii fi bi ẹṣẹ ti buru jọjọ to hàn; o fi bi iṣẹ naa ti nira to ani fun Agbara Ayeraye, lati gba ẹlẹṣẹ la kuro ninu ayọrisi riru ofin Ọlọrun. Jesu wo iran eniyan ti o kẹyin, O ri aye ti o wa ninu iru itanjẹ kan naa ti o fa iparun Jerusalẹmu. Ẹṣẹ nla ti awọn Ju ṣẹ ni wipe wọn kọ Kristi silẹ; ẹṣẹ nla ti awọn Kristẹni yoo jẹ kikọ ofin Ọlọrun silẹ, ipilẹ ijọba Rẹ ni ọrun ati aye. A yoo gan ìlana Jehofa, a yoo si sọ di asan. Ọgọọrọ awọn eniyan ti wọn wa ninu igbekun ẹṣẹ, ti wọn jẹ ẹru Satani, ti o daju wipe wọn yoo jiya iku ẹẹkeji ni yoo kọ lati gbọ ọrọ otitọ ni ọjọ ibẹwo wọn. Ifọloju ti o banilẹru! Iraniye ti o ṣajeji. ANN 7.3

Ọjọ meji ṣaaju ajọ Irekọja, nigbati Kristi ti kuro ni tẹmpili fun igba ikẹyin, lẹyin ti O ti ba agabagebe awọn adari awọn Ju wi, O jade pẹlu awọn ọmọ ẹyin Rẹ lọ si oke Olifi, O si joko ni ori pápá ni odikeji ilu naa. Lẹẹkansi O wo tẹmpili naa pẹlu ogo didan rẹ, ade ẹwa ti o de ori oke mimọ naa. ANN 7.4

Ni ẹgbẹrun ọdun kan sẹyin, onísáamù ti kókìkí aanu Ọlọrun fun Israeli ni fifi ile mimọ Israeli ṣe ibugbe Rẹ: “Ni Salẹmu pẹlu ni agọ Rẹ wa, ati ibujoko Rẹ ni Sioni.” O “yan ẹya Juda, oke Sioni ti O fẹ. O si kọ ibi mimọ Re bi aafin ti o ga.” O. Dafidi 76:2; 78:68, 69. A kọ tẹmpili akọkọ ni àkókò ti nǹkan n lọ deede julọ ninu itan Israeli. Iṣura ti o pọ yanturu ni ọba Dafidi ko pamọ fun iṣẹ yii, a kọ iwe ilana ile naa ni abẹ imisi Ọlọrun. 1 Kronika 28:12, 19. Solomoni, ọba ti o gbọn julọ ninu awọn ọba Israeli ni o pari rẹ. Tẹmpili naa ni ile ti o logo julọ lori ilẹ aye yii. Sibẹ Ọlọrun kede nipasẹ woli Hagai nipa tẹmpili naa pe: “Ogo ile ikẹyin yii yoo tobi ju ti iṣaaju lọ.” “Emi yoo si mi gbogbo orilẹ ede, Ifẹ inu gbogbo awọn orilẹ ede yoo si de: Emi yoo si fi ogo kun ile yii, bẹẹni Oluwa awọn ọmọ ogun wi.” Hagai 2:9, 7. ANN 7.5

Lẹyin igba ti Nebukadnesa pa tẹmpili naa run, awọn eniyan ti wọn pada lati oko ẹru ọlọjọ pipẹ, wa si orilẹ ede ti o ti di ahoro naa, ti awọn eniyan ti fẹrẹ sa kuro nibẹ tan, wọn tun un kọ́ ni bii ọdẹgbẹta (500) ọdun ṣaaju ibi Kristi. Awọn arugbo ti wọn ri ogo tẹmpili Solomoni wa ninu wọn, wọn sọkun nigbati wọn n fi idi ile tuntun lelẹ nitori pe ko rẹwa to ile ti iṣaaju. Woli naa ṣe alaye ero ti o wọpọ nigba naa bayii pe: “Tani o kù ninu yin ti o ri ile yii ninu ogo rẹ akọkọ? Bawo ni ẹ ti ṣe ri nisinsinyii? Ko ha dabi asan ni oju yin bi a ba fi wọn we ara wọn?” Hagai 2:3; Esra 3:12. Nigba naa ni a ṣe ileri wipe ogo ti ikẹyin yoo ju ti iṣaaju lọ. ANN 7.6

Ṣugbọn tẹmpili keji ko logo to ti iṣaaju; bẹẹni ko ni awọn ohun ti a le fi oju ri ti wọn ṣe afihan iwapẹlu Ọlọrun ti wọn wa ninu tẹmpili akọkọ. Ko si ifihan agbara Ọlọrun ni àkoko ti a ya a si mimọ. A ko ri ki ikuuku ogo o kún inu tẹmpili tuntun naa. Ina kankan ko sọkale lati ọrun wa lati jo ẹbọ lori pẹpẹ. Ko si Shekina laarin awọn kerubu ninu ibi mimọ julọ; ko si apoti ẹri, itẹ aanu ati walaa majẹmu nibẹ mọ. Ko si ohùn ti o kọ lati ọrun lati fi ifẹ Jehofa han fun alufa. ANN 7.7

Fun ọpọlọpọ ọdun awọn Ju ti n ṣe akitiyan ṣugbọn laisi ayọrisi lati fihan ibi ti ileri Ọlọrun ti Hagai sọ yoo ti di mimuṣẹ; sibẹ igberaga ati aigbagbọ ra wọn niye lati mọ itumọ gan ti ọrọ woli naa ni. A ko bu ọla fun tẹmpili keji pẹlu ikuuku ogo Jehofa bikoṣe pẹlu iwapẹlu Ẹni ti kikun Ọlọrun n gbe inu Rẹ ninu ara—ti O jẹ Ọlọrun funra Rẹ ti a fihan ninu ẹran ara. “Ifẹ awọn orilẹ ede” wa sinu tẹmpili Rẹ nitooto nigba ti Ọkunrin Nasarẹti n kọni ti O si n wonisàn ninu ile mimọ naa. Nitori pe Kristi wa sinu rẹ, ati ninu eyi nikan ṣoṣo ni tẹmpili keji fi ni ogo ju ti iṣaaju lọ. Ṣugbọn Israeli ti le Ẹbun ọrun jinna si ara rẹ. Pẹlu bi Olukọ onirẹlẹ naa ti jade kuro lẹnu ilẹkun oniwura rẹ, ni ọjọ naa ni ogo fi ile naa silẹ titi lae. Nigba naa ni ọrọ Olugbala wa si imuṣẹ wipe: “A fi ile yin silẹ fun yin ni ahoro.” Matiu 23:28. ANN 8.1

Awọn ọmọlẹyin Kristi kun fun ibẹru ati iyalẹnu pẹlu asọtẹlẹ Kristi nipa iparun tẹmpili naa, wọn si fẹ lati mọ awọn itumọ ọrọ Rẹ ni kikun. Ọrọ̀, iṣẹ ati ọgbọn ikọle ni a lo sori ile naa lati le jẹ ki ogo rẹ o pọ si. Ọba Hẹrọdu Nla ná ọrọ̀ awọn Romu ati awọn Ju sori tẹmpili naa ni ọna akoyawọ. Ani olori ijọba aye bukun fun pẹlu awọn ẹbun rẹ. Awọn okuta mabu ti wọn funfun ti wọn si tobi jọjọ ti a ko wa lati Romu nitori rẹ, wa lara ohun ti a fi kọ ọ. Awọn okuta wonyi ni awọn ọmọ ẹyin pe akiyesi Ọga wọn si wipe: “Wo iru okuta ati iru ile ti o wa nihin yii!” Maku 13:1. ANN 8.2

Jesu fesi si awọn ọrọ wọnyi lọna to lọwọ ti o si yanilẹnu: “Lootọ ni mo wi fun yin, ki yoo si okuta kan nihin yii ti a o fi silẹ lori ekeji, ti a ki yoo wo lulẹ.” Matiu 24:2. ANN 8.3

Awọn ọmọ ẹyin so iparun Jerusalẹmu papọ mọ awọn iṣẹlẹ ipadabọ Jesu ninu ogo lati wa gba itẹ ijọba aye, ki O si ṣe idajọ awọn Ju ti ko ronupiwada, ki O si gba orilẹ ede naa kuro lọwọ ajaga Romu. Oluwa ti sọ fun wọn pe Oun n padabọ lẹẹkeji. Nitori naa, nigba ti a mẹnuba idajọ lori Jerusalẹmu, ọkan wọn lọ si ibi ipadabọ naa; bi wọn si ṣe yi Olugbala po ni ori oke Olifi, wọn beere: “Nigba wo ni awọn nnkan wọnyi yoo ṣẹ? Ati kini yoo jẹ ami wiwa Rẹ ati ti opin aye?” Ẹsẹ 3. ANN 8.4

Ninu aanu a ṣiji bo ọjọ iwaju kuro loju awọn ọmọ ẹyin. Bi awọn nnkan buburu meji ba ye wọn yékeyeke nigba yẹn—ijiya ati iku Olurapada ati iparun ilu wọn ati tẹmpili—ipaya a bo wọn mọlẹ. Kristi ṣe alaye awọn iṣẹlẹ pataki ti yoo ṣẹlẹ ṣaaju opin àkókò fun wọn. Ọrọ Rẹ ko ye wọn daradara nigba naa; ṣugbọn a o la itumọ rẹ ye awọn eniyan Rẹ bi wọn ba ṣe nilo awọn ẹkọ to wa ninu rẹ. Asọtẹlẹ ti O sọ ní oriṣi itumọ meji; nigba ti o sọ nipa iparun Jerusalẹmu, o tun ṣe apẹẹrẹ awọn ajalu ọjọ nla ti o kẹyin. Jesu kede idajọ ti yoo wa si ori Israeli alaigbọran si etigbọ awọn ọmọ ẹyin, paapaa julọ idajọ igbẹsan ti yoo wa si ori wọn fun kikọ Mesaya silẹ ati fun kikan An mọ agbelebu. Awọn ami ti ko ṣe e ṣimọ ni yoo wa ṣaaju opin ti o lẹru naa. Akoko buburu yoo yara wá kankan ati lọgan. Jesu tun kilọ fun awọn atẹle Rẹ pe: ” Nigba ti ẹyin ba ri ikorira ti isọdahoro, ti a ti ẹnu woli Daniẹli sọ, ti o ba duro ni ibi mimọ (ẹni ti o ba ka a, ki oye ki o ye:) nigba naa ni ki awọn ti n bẹ ni Judea o salọ si awọn ori oke.” Matiu 24:15, 16; Luku 21:20, 21. Nigba ti a ba gbe ọpagun abọriṣa awọn ara Romu ró sori ilẹ mimọ, eyi ti o jinna diẹ si odi ilu, nigba naa ni ki awọn atẹle Kristi o wa aabo nipa fífi ẹsẹ fẹ. Nigba ti wọn ba ti ri ami ikilọ, gbogbo awọn ti wọn ba fẹ sa asala ko gbọdọ dẹsẹ duro. A nilati ṣe igbọran si ami ikilọ lati salọ ni gbogbo ilẹ Judea ati ni Jerusalẹmu funra rẹ lọgan. Ẹni ti o ba wa ni ori ile ko gbọdọ sọkalẹ wọ inu ile, ani lati mu ohun ti o ṣe iyebiye julọ. Awọn ti wọn ba n ṣiṣẹ ninu oko tabi ọgba ajara ko gbọdọ pada lati mu aṣọ ti wọn bọ kalẹ nigba ti wọn n ṣiṣẹ ninu ooru ọjọ naa. Wọn ko gbọdọ lọra fun iṣẹju kan ki wọn ma baa ni ipin ninu iparun gbogboogbo naa. ANN 8.5

Ki i ṣe wipe a ṣe Jerusalẹmu lọṣọ nikan ni ni akoko ijọba Hẹrọdu, ṣugbọn pẹlu kikọ awọn ile iṣọ, ogiri ati odi alagbara, ni afikun pẹlu agbara ibi ti a tẹ ilu naa do si, o di ilu ti a ko le fi ipa wọ. Ni asiko yii, ẹnikẹni ti yoo ba sọ asọtẹlẹ iparun rẹ ni gbangba, yoo dabi atanilọyẹ ti n ya were ni bii Noah ni akoko rẹ. Ṣugbọn Kristi ti sọ wipe: “Ọrun ati aye yoo kọja lọ, ṣugbọn ọrọ Mi ki yoo kọja lọ.” Matiu 24:35. Nitori awọn ẹṣẹ rẹ, a ti kede ibinu nla le Jerusalẹmu lori, orikunkun aigbagbẹ rẹ si jẹ ki o daju. Oluwa ti sọ nipasẹ woli Mika pe: “Gbọ eyi Emi bẹ yin, ẹyin olori ni Jakọbu, ati ẹyin alakoso ile Israeli ti o korira idajọ, ti o si n yi otitọ pada. Wọn fi ẹjẹ kọ Sioni ati Jerusalẹmu pẹlu aiṣedeede. Awọn olori rẹ n ṣe idajọ nitori abẹtẹlẹ, awọn alufa rẹ n kọni nitori owo iṣẹ, awọn woli rẹ n sọtẹlẹ fun owo: sibẹ wọn o ha gbẹkẹle Oluwa, ki wọn si wipe, Oluwa ko ha wa laarin wa bi? ibi kan ki yoo ba wa.” Mika 3:9—11. ANN 8.6

Awọn ọrọ wọnyi ṣe alaye ni pipe iwa ibajẹ ati ododo ara ẹni awọn olugbe Jerusalẹmu. Nigba ti wọn n sọ wipe wọn n tẹle ilana ofin Ọlọrun láìyẹsẹ, wọn n ru gbogbo agbekalẹ ofin. Wọn korira Kristi nitori iwa mimọ ati ailabawọn Rẹ fi aiṣedeede wọn han; wọn si fi ẹsun kan-An wipe Oun ni O ṣe okunfa gbogbo isoro ti o de ba wọn ni ijiya fun ẹṣẹ wọn. Bi o tilẹ jẹ wipe wọn mọ Ọ ni alailẹṣẹ, wọn sọ wipe iku Rẹ ṣe pataki fun aabo orilẹ ede wọn. Awọn adari Ju wipe, “Bi a ba fi I silẹ, gbogbo eniyan yoo gba A gbọ: awọn ara Romu yoo si wa gba ilẹ ati orilẹ ede wa pẹlu.” Johanu 11:48. Bi a ba jọwọ Kristi lọwọ fun pipa wọn le jẹ eniyan ti o lagbara ti o tun wa niṣọkan lẹẹkan si. Wọn ba ronu bẹẹ, wọn wa fi ohun ṣọkan ninu ipinu olori alufaa, wipe o san ki ẹnikan o ku ju ki gbogbo orilẹ ede o ṣegbe lọ. ANN 9.1

Bayii ni awọn adari Ju ṣe kọ “Sioni pẹlu ẹjẹ, ati Jerusalẹmu pẹlu aiṣedeede.” Mika 3:10. Ati pẹlu, nigba ti wọn pa Olugbala wọn nitori pe O ba ẹṣẹ wọn wi, ododo ara ẹni wọn pọ debi wipe wọn si ri ara wọn gẹgẹ bi eniyan ti Ọlọrun ṣaanu fun, wọn si n reti ki Oluwa gba wọn lọwọ awọn ọta wọn. Woli naa tẹsiwaju wipe: “Nitori naa, nitori yin ni a o ṣe ro Sioni bi oko, Jerusalẹmu yoo di okiti ati oke nla ile bi ibi giga igbo.” Ẹsẹ 12. ANN 9.2

Fun bi ogoji ọdun lẹyin ti Kristi ti funra Rẹ kede iparun Jerusalẹmu, Oluwa fa idajọ Rẹ lori ilu ati orilẹ ede naa sẹyin. Ipamọra Ọlọrun lori awọn ti wọn kọ iyinrere Rẹ silẹ, ti wọn tun pa Ọmọ Rẹ jẹ eyi ti o yanilẹnu. Owe igi ti ko so eso ṣe afihan ibaṣepọ Ọlọrun pẹlu orilẹ ede Ju. Aṣẹ naa ti jade wa, “gee lulẹ, eeṣe ti o fi n gba ilẹ lasan?” (Luku 13:7) ṣugbọn aanu Ọlọrun si fi wọn silẹ fun igba diẹ. Ọpọlọpọ si wa laarin awọn Ju ti ko ni oye nipa iwa ati iṣẹ Kristi. Ati pe, awọn ọmọ koi tii jẹ anfani tabi gba imọlẹ ti awọn òbi wọn kẹgan. Nipasẹ iwaasu awọn apostoli ati awọn ẹmẹwa wọn, Ọlọrun yoo jẹ ki imọlẹ o tan si wọn; a yoo jẹ ki wọn o ri bi asọtẹlẹ ti ṣe di mimuṣẹ, ki i ṣe ninu ìbí ati igbesi aye Kristi nikan, ṣugbọn ninu iku ati ajinde Rẹ. A ko dá awọn ọmọ lẹbi nitori ẹṣẹ awọn obi wọn; ṣugbọn pẹlu oye nipa gbogbo imọlẹ ti a fun awọn obi wọn, ti awọn ọmọ tun kọ awọn imọlẹ ti a fifun wọn ni afikun silẹ, wọn di alabapin ẹṣẹ awọn obi wọn, wọn si kun odiwọn ẹṣẹ awọn obi wọn de ẹnu. ANN 9.3

Ipamọra Ọlọrun si Jerusalẹmu tubo n jẹ ki wọn yigbì ninu aironupiwada si ni. Ninu ikorira ati iwa ika wọn si awọn ọmọ ẹyin Jesu, wọn kọ ipe aanu ikẹyin silẹ. Nigba naa ni Ọlọrun mu aabo Rẹ kuro lori wọn, O si mu agbara ti n kawọ Satani ati awọn angẹli rẹ ko kuro. A wa fi orilẹ ede naa silẹ fun akoso olórí ti o yan. Awọn ọmọ rẹ ti gan oore ọfẹ Kristi eyi ti i ba kawọ ero buburu wọn kò, awọn wọnyi ni wọn wa ṣẹgun wọn. Satani wa ru eyi ti o gbona ti ko si ni ironu julọ ninu ifẹkufẹ ọkan wọn soke. Awọn eniyan ko ronu; wọn ti kọja ironu—oofa ọkan ati ibinu ti ko nitumọ ni o n dari wọn. Wọn dabi Satani ninu iwa ika wọn. Ainifọkantan, owú, ikorira, ija, iṣọtẹ, ati ipaniyan ni o wa laarin wọn, ninu idile, ati ni orilẹ ede, laarin awọn ti wọn ga julọ ati laarin awọn ti wọn kere julọ. Ko si aabo nibi kankan. Awọn ọrẹ ati ibatan n dalẹ ara wọn. Awọn obi n pa awọn ọmọ wọn, bẹẹni awọn ọmọ n pa awọn obi wọn. Awọn adari awọn eniyan naa ko ni agbara lati ṣe akoso ara wọn. Oofa ọkan ti ko ni akoso sọ wọn di onroro. Awọn Ju gba ẹri eke lati da Ọmọ Ọlọrun alaiṣẹ lẹbi. Bayii ifẹsunkanni lọna eke ko jẹ ki aye wọn o nitumọ. Nipa iṣẹ wọn, wọn ti n sọ ọ lati igba pipẹ wa wipe: “Jẹ ki Ẹni Mimọ Israeli o kuro niwaju wa.” Aisaya 30:11. Bayi a fi ifẹ ọkan wọn fun wọn. Ibẹru Ọlọrun ko di wọn lọwọ mọ. Satani ti di olori orilẹ ede naa, awọn alakoso ilu ati ẹsin wa labẹ isakoso rẹ. ANN 9.4

Ni igba miran awọn olori ẹgbẹ alatako a parapọ lati ko ẹru awọn ti wọn wa ninu ahamọ wọn, ti wọn a si fiya jẹ wọn, wọn a bá ara wọn ja wọn a si pa ara wọn ni ipakupa ailaanu. Ani wipe tẹmpili jẹ mimọ ko dawọ iwa onroro buburu wọn duro. A pa awọn olujọsin niwaju pẹpẹ, a si sọ ibi mimọ di aimọ pẹlu oku awọn ti a pa. Sibẹ ninu ifọju ati iyaju sọ ọrọ òdì wọn, awọn ti n wu iwa ika yii n sọ ọ ni gbangba wipe wọn ko ni ibẹru wipe a o pa Jerusalẹmu run nitori pe ilu Ọlọrun funra Rẹ ni. Lati le fi idi agbara wọn mulẹ daradara, wọn fun awọn woli eke ni owo abẹtẹlẹ, ani nigba ti awọn ọmọ ogun Romu n dó ti tẹmpili, lati le kede ki awọn eniyan o duro de igbala lati ọdọ Ọlọrun. Titi ti gbogbo rẹ fi pari, awọn eniyan gbagbọ wipe Ẹni Giga julọ yoo ja fun wọn lati ṣẹgun awọn ọta wọn. Ṣugbọn Israeli ti fi ẹgan kọ aabo Ọlọrun silẹ, bayi ko ni aabo. Jerusalẹmu ti o yẹ ki a kaanu fun! ti a faya latari ija abẹle, ẹjẹ awọn ọmọ rẹ ti wọn funra wọn ṣe iku pa ti sọ awọn adugbo rẹ di alawọ pupa fòò, nigba ti awọn ọmọ ogun ajeji n wọ awọn odi rẹ ti wọn si n pa awọn ọmọ ogun rẹ. ANN 10.1

Gbogbo awọn asọtẹlẹ ti Jesu sọ nipa iparun Jerusalẹmu ni wọn wa si imuṣẹ patapata. Awọn Ju ni iriri otitọ awọn ọrọ ikilọ rẹ: “Iru oṣuwọn ti ẹyin ba fi wọn, oun ni a o fi wọn fun yin.” Matiu 7:2. ANN 10.2

Awọn ami ati iṣẹ iyanu ṣẹlẹ ti wọn sọ nipa ajalu ati iparun ti n bọ. Laarin oru, imọlẹ ti ki i ṣe lasan tan si ori tẹmpili ati pẹpẹ. Lori ikuuku awọsanma nigba ti oorun n wọ, a ri aworan awọn kẹkẹ ẹṣin ati awọn jagunjagun ti wọn n ko ara wọn jọ pọ fun ogun. Awọn ìró ti wọn ṣeni ní kàyéfì dẹru ba awọn alufa ti wọn n jọsin ninu ibi mimọ ni alẹ; ilẹ mì, a si gbọ ohùn pupọ ti n kigbe wipe: “Ẹ jẹ ki a kuro nibi.” Ilẹkun nla ti o wa ni iha ila oorun, ti o wuwo debi wipe o maa n nira fun bi ogun eniyan lati pádé, ti a si fi awọn irin nla de mọ okuta ti o le koko ni o ṣi silẹ ni oru ọganjọ lairi ohun ti o ṣi. ANN 10.3

Fun ọdun meje ọkunrin kan n lọ sókè sódò kaakiri awọn adugbo Jerusalẹmu, o n kigbe iparun ti yoo wa si ori ilu naa. O n kọ orin arò lọsan ati loru bayi pe: “Ohùn kan lati ila oorun wa! ohun kan lati iwọ oorun wa! ohùn kan lati afẹfẹ mẹrẹẹrin! Ohùn kan ti o tako Jerusalẹmu ati tẹmpili! ohùn kan ti o tako ọkọ iyawo ati iyawo! ohùn kan ti o tako gbogbo eniyan!” A ti ẹni ajeji yii mọ inu tubu, a si nàá, ṣugbọn ko ṣe àròyé kan. Idahun rẹ si ifiyajẹni ati iwọsi ti a fi kan-an ni wipe: “Ègbé, ègbé ni fun Jerusalẹmu!” “egbe, egbe ni fun awọn olugbe inu rẹ!” Ko dawọ igbe ikilọ rẹ duro titi ti a fi pa a ninu ìdóguntì ti o sọtẹlẹ. ANN 10.4

Ko si Kristẹni kankan ti o ṣegbe sinu iparun Jerusalẹmu. Kristi ti ki awọn ọmọ ẹyin Rẹ nilọ, gbogbo awọn ti wọn gba ọrọ Rẹ gbọ ni wọn wọna fun ami ti O ṣeleri. Jesu wipe, “Nigba ti ẹyin ba ri ti awọn ẹgbẹgun yi Jerusalẹmu ka, ki ẹ mọ wipe iparun rẹ ti sunmọ etile. Ki ẹni ti o wa ni Judea o salọ si awọn òkè; ki awọn ti wọn wa laarin rẹ o jade kuro.” Luku 21:20, 21. Lẹyin ti awọn Romu labẹ Cestius yi ilu naa ka, lairotẹlẹ wọn fi ibudo wọn silẹ nigba ti ohun gbogbo mu ki o rọrun fun wọn lati ṣe akọlu. Awọn ti a d‘ógun tì, tí atako ṣiṣe ti su ti fẹrẹ juwọ silẹ, nigba ti olori ogun awọn Romu ṣàdédé fa awọn ọmọ ogun rẹ sẹyin laisi idi kan pato. Ṣugbọn aanu Ọlọrun ni o n ṣe akoso awọn iṣẹlẹ fun rere awọn eniyan Rẹ. A ti fi ami ti a ṣeleri han fun awọn Kristẹni ti n sọna, bayi anfani ti ṣi silẹ fun gbogbo ẹni ti o ba fẹ lati ṣe igbọran si ikilọ Jesu. Awọn iṣẹlẹ yii ṣe rẹgi to bẹẹ gẹẹ ti ko fi si eyikeyi ninu awọn Ju tabi awọn Romu ti o le dí awọn Kristẹni lọwọ ninu asala wọn. Nigba ti Cestius n pada sẹyin, awọn Ju sa tẹle awọn ọmọ ogun rẹ; nigba ti awọn mejeeji n wọya ija, awọn Kristẹni ni anfani lati fi ilu naa silẹ. Ko si ọta kankan ni ẹyin odi ilu ni akoko yii lati da wọn duro. Ni akoko idogun tì yii, awọn Ju n pejọ pọ si Jerusalẹmu lati ṣe ajọdun Ajọ Agọ, bayii ni awọn Kristẹni ṣe ri àyè salọ laisi idiwọ. Laifi ẹsẹ falẹ, wọn salọ si ibi aabo—ilu Pella, ni ilẹ Perea, ni ikọja Jordani. ANN 10.5

Awọn ẹgbẹgun Ju ti wọn n sa tẹle Cestius ati awọn ọmọ ogun rẹ lẹyin, kọlu wọn latẹyin wa pelu ero lati pa wọn run patapata. Pẹlu inira nla ni awọn Romu fi le fasẹyin tan patapata. Awọn Ju si pada sile pẹlu ikogun wọn, wọn si wọ Jerusalẹmu pẹlu iṣẹgun laisi adanu kan to dabi alara. Ṣugbọn ibi lasan ni aṣeyọri wọn yii ko ba wọn. O fun wọn ni ẹmi orikunkun ati atako si awọn ara Romu eyi ti o mu iparun ti ko se e sọ ba ilu ti a ti fi gegun naa. ANN 10.6

Ijamba ti o banilẹru ni o subu lu Jerusalẹmu nigba ti Titu pada do ti ilu naa. Orisirisi eto ni wọn n lọ ninu ilu naa ni akoko ajọ Irekọja, nigba ti ọpọlọpọ awọn Ju pejọ pọ sinu ogiri rẹ. Àká ounjẹ wọn, eyi ti o ba jẹ wipe bi wọn bá lo o daradara i ba to wọn fun ọpọ ọdun, ni a ti kọkọ fi ṣofo latari owú ati igbẹsan awọn onijagidijagan, ni bayi wọn wa ni gbogbo iriri ipaya ebi. A ta oṣuwọn ọka kan fun iwọn talẹnti kan. Ijiya ebi naa pọ to bẹẹ gẹẹ ti awọn eniyan n ge awọ igbanu, bata, ati ti ibori wọn je. Ọpọ eniyan yoo yọ kẹlẹ jade lalẹ lati lọ wa awọn eweko to wa lẹyin odi ilu, bi o tilẹ jẹ wipe ọpọ ninu wọn ni a mu ti a pa pẹlu ifiyajẹni kikoro, ni ọpọ igba, a maa n fi ipa gba eyi ti awọn ti wọn ba pada de ni alaafia ba ri lọwọ wọn, bi o tilẹ jẹ wipe wọn fi ẹmi ara wọn wewu. Ijiya ti o buru jai ni awọn ti wọn ba ni agbara fi maa n jẹ awọn alaini eniyan lati le fi ipa gba ounjẹ perete ti wọn ba ni ni ipamọ. Awọn ti wọn ba ti jẹun yo ni wọn saba maa n wu iru iwa ika yii pẹlu erongba lati le ri ounjẹ ko pamọ fun ọjọ iwaju. ANN 11.1

Ẹgbẹgbẹrun ni wọn padanu ẹmi wọn nitori iyan ati ajakalẹ arun. O dabi ẹnipe ifẹ si ara ẹni ti parun tan. Awọn ọkọ n ja iyawo wọn lole, bẹẹ ni awọn iyawo n ṣe pẹlu. Awọn ọmọ a maa ja ounjẹ gba kuro lẹnu awọn obi arugbo wọn. Ibeere woli naa wipe, “Njẹ obirin ha le gbagbe ọmọ omu rẹ”? ri idahun laarin odi ilu ti iparun de ba naa: “Owo awọn obinrin alaanu ti sé awọn ọmọ tikara wọn: awọn wọnyi ni ohun jijẹ fun wọn ni igba wahala ọdọmọbinrin awọn eniyan mi.” Aisaya 49:15; Ẹkun Jeremaya 4:10. Bẹẹ ni a mu ikilọ asọtẹlẹ ti a ṣe ni ẹgbeje (1400) ọdun sẹyin wa si imuṣẹ: “Obinrin ti awọ rẹ tutu ninu yin ti o si ṣe ẹlẹgẹ, ti ko jẹ da aṣa àti fi atẹlẹsẹ rẹ kan ilẹ nitori ikẹra ati iwa ẹlẹgẹ, oju rẹ yoo koro si ọkọ ookan aya rẹ, ati si ọmọ rẹ okunrin, ati ọmọ rẹ obinrin, . . . ati si awọn ọmọ rẹ ti yoo bi; nitori pe oun o jẹ wọn ni ikọkọ nitori aini ohunkohun; ninu ìdótì ati ihamọ naa, ti ọta rẹ yoo ha ọ mọ ni ibode rẹ.” Deuteronomi 28:56, 57. ANN 11.2

Awọn adari Romu ṣe akitiyan lati fiya jẹ awọn Ju ki wọn baa le juwọ silẹ. A na awọn ẹlẹwọn ti wọn ṣe agidi nigba ti a mu wọn, a fiya jẹ wọn a si kan wọn mọ agbelebu niwaju ogiri ilu naa. Ọgọrọrun ni a n ṣe bayi pa lojoojumọ, ti iṣẹ to n dẹru bani yii si n tẹsiwaju titi ti Afonifoji Jehosafati ati Kalfari fi kun fun agbelebu debi wipe ko si àyè lati kọja laarin wọn. Ọna ti o buru patapata gbaa ni a fi bẹ egun ti a sọ jade niwaju àga idajọ Pilatu wò: “Ki ẹjẹ Rẹ o wà lori wa, ati awọn ọmọ wa.” Matiu 27:25. ANN 11.3

Titu i ba mọọmọ fi opin si iṣẹlẹ buburu yii ti Jerusalẹmu i ba masi jiya idajọ rẹ ni kikun. Ipaya mu bi o ṣe ri awọn oku ni okiti ninu awọn afonifoji. A fi bi ẹni ti o wa ninu iran, o wo tẹmpili ologo naa lati oke Olifi wa o si paṣẹ pe ki a maṣe fi ọwọ kan ọkan ninu awọn okuta rẹ. Ki o to ṣe akitiyan lati gba ilu olodi yii, o ṣipẹ fun awọn adari Ju lati maṣe kan an nipa fun òhun lati sọ ibi mimọ wọn di aimọ pẹlu ẹjẹ. Bi wọn yoo ba jade wa lati wa ja nibomiran, ara Romu kan ki yoo ba tẹmpili mimọ naa jẹ. Josefọsi funra rẹ rọ wọn ni ọna ti o muni lọkan julọ lati juwọ silẹ, lati gba ara wọn, ilu wọn ati ibi ijọsin wọn silẹ. Ṣugbẹn egun kikoro ni wọn fi da a lohun, a sọ òkò lu olubalaja eniyan wọn ti o kẹyin, bi o ti n bẹbẹ pẹlu wọn. Awọn Ju ti kọ ipẹ Ọmọ Ọlọrun silẹ, ni akoko yii iṣaroye ati ẹbẹ a tilẹ se ọkan wọn le si lati ṣe atako titi de opin ni. Pabo ni akitiyan Titu lati daabo bo tẹmpili naa ja si; Ẹni ti o tobi ju u lọ ti sọ wipe a ki yoo fi okuta kan lelẹ lori ekeji. ANN 11.4

Agidi awọn adari awọn Ju ati iwa ọdaran to buru jai ti wọn n wu ninu ilu ti a dó tì yii ru ibinu ati ikorira awọn ara Romu soke, lẹyin-ọrẹyin Titu pinu lati fi ibinu kọlu tẹmpili naa. O si pinu sibẹ wipe bi o ba ṣe e ṣe a ki yoo pa a run. Ṣugbọn a ko ṣe igbọran si aṣẹ rẹ. Lẹyin igba ti o wọ inu agọ rẹ lọ lalẹ, awọn Ju jade wa lati inu tẹmpili wọn lati kọlu awọn ọmọ ogun ti wọn wa ni ita. Ninu ijakadi yii, ọmọ ogun kan ju igi ina lati ẹnu ilẹkun wa, lọgan bi awọn yara ti a fi igi kedari ṣe lọṣọ ninu ile mimọ naa ṣe gbina niyẹn. Titu sare lọ sibẹ pẹlu awọn adari ogun rẹ, o si paṣẹ ki awọn ọmọ ogun o pa ina naa. Wọn ko da a lóhùn. Ninu ibinu wọn, awọn ọmọ ogun ju igi ina sinu awọn iyàrá ti wọn wà lẹbaa tẹmpili naa, lẹyin eyi wọn fi idà wọn pa ọpọlọpọ awọn ti wọn wa aabo si ibẹ. Ẹjẹ n san lori awọn atẹgun bi omi. Ẹgbẹẹgbẹrun awọn Ju ni wọn ṣegbe. Ninu ariwo ogun naa, a gbọ ọpọlọpọ ohun ti n kigbe wipe: “Ìkábódì!”—ogo ti kuro. ANN 11.5

“Titu ri wipe ko ṣe e ṣe ki oun o dawọ ibinu awọn ọmọ ogun naa duro; oun pẹlu awọn oṣiṣẹ rẹ wọ inu tẹmpili naa, wọn si yẹ inu rẹ wo. Ẹwa rẹ ya wọn lẹnu, niwọn igba ti ina koi tii wọ inu ibi mimọ, o ṣa ipa ikẹyin lati da a si, o sare jade lẹẹkan si lati ba awọn ọmọ ogun rẹ sọrọ lati pa ina naa. Olori ogun ọrun Liberalis fẹ fi ipa mu wọn ṣegbọran; ṣugbọn apọnle wọn fun olootu ijọba ko ni itumọ loju ikorira wọn si awọn Ju, ifẹ lati jagun ati ireti lati ri ikogun. Awọn ọmọ ogun ri ohun gbogbo to yi wọn ka bi wọn ti n dan gbinrin pẹlu wura, ti wọn tun dan si nitori ina ti n jo; wọn ro ni ọkan wọn pe isura ti ko ṣe e ṣiro ni a to jọ sinu ibi mimọ. Ọmọ ogun kan ti a ko fiyesi fi ṣugudu ti n jona si ara ilẹkun: gbogbo ile naa ni o gbina lọwọ kan. Eefin ti o dudu pẹlu ina ni o lé awọn ọgagun jade, bẹẹ ni a fi ile ọlọwọ naa silẹ fun atubọtan rẹ. ANN 12.1

Iṣẹlẹ yii jẹ eyi ti o buru ni oju awọn ara Romu, kini yoo jẹ si awọn ara Ju? Ori oke ti o n ṣe akoso ilu naa n jona bi oke onina ti n ṣe eefin. Ni meni meji ni gbogbo ile naa subu pẹlu ariwo nla ti ina si bo gbogbo wọn. Awọn orule ti a fi kedari ṣe dabi ọwọ ina; awọn ṣonṣo ori tẹmpili dabi ina nla; awọn ilẹkun ile iṣọ n ju ọwọ ina ati eefin soke. Awọn oke ti wọn yi i ka mọlẹ; awọn eniyan si ko ara wọn jọ pọ lẹlẹgbẹjẹgbẹ, wọn n woran pẹlu ibanujẹ ọkan bi iparun naa ti n tẹsiwaju: ogiri ati ẹba oke ilu naa kun fun awọn eniyan, oju awọn kan kọrẹ lọwọ nitori ẹdun ọkan, nigbati awọn miran n kigbe ẹsan ti ko nitumọ. Ariwo awọn ọmọ ogun Romu bi wọn ti n sare lọ soke sodo, pẹlu igbe awọn alajakuakata ti wọn n ṣegbe ninu ina dapọ mọ iro ina ati iro iṣubu awọn igi nla nla. Awọn oke da iro igbe awọn ti wọn wa lori oke pada; ni gbogbo akoko yii, awọn ogiri n da iro igbe ati ẹkun pada. Awọn ti wọn ti fẹrẹ kú nitori ìyàn lo gbogbo agbara ti o ku ninu wọn lati kigbe arò ati iparun. ANN 12.2

“Ipakupa ti o n lọ ninu ile tilẹ tun buru jai ju bi a ti ri lati ita lọ. Ọkunrin ati obinrin, agba ati ọmọde, awọn alakatakiti ati awọn alufa, awọn ti wọn n jà ati awọn ti wọn bẹbẹ fun aanu ni a ge lulẹ laidákansí. Iye awọn ti a pa pọ ju ti awọn ti n pani lọ. Awọn ọmọ ogun nilati gun ori okiti awọn ti wọn ti ku kọja ki wọn ba le tẹsiwaju ninu iṣẹ iparun wọn.” ANN 12.3

Lẹyin iparun tẹmpili naa, gbogbo ilu naa subu si ọwọ awọn ara Romu ni kia. Awọn adari Ju sa kuro ninu awọn ile iṣọ agbara wọn ti Titu si ba wọn ti wọn ṣofo. O yọju wo wọn pẹlu iyanu o si sọ wipe Ọlọrun ti fi wọn le oun lọwọ; nitori ko si iru ẹrọ naa bi o ti wu ki o lagbara to ti o le bori awọn odi alagbara rẹ. A wó ilu ati tẹmpili naa palẹ de ipilẹ wọn, a si ro ilẹ naa ti ibi mimọ duro le lori “bi oko.” Jeremaya 26:18. O le ni milliọnu kan awọn Ju ti wọn ṣegbe ninu idogunti naa ati ipaniyan ti o tẹle; a ko awọn ti ko ku ninu ogun ni igbekun, a ta wọn bi ẹru, a wọ wọn lọ si Romu lati ṣe ayẹsi iṣẹgun aṣẹgun wọn, a ju wọn si ẹranko ninu gbọngan igbafẹ, a fọn wọn kaakiri gbogbo aye bi alainile. ANN 12.4

Awọn Ju ni won ro ṣẹkẹṣẹkẹ ara wọn; awọn funra wọn ni wọn kun ago ijiya wọn. Wọn n kore ohun ti ọwọ wọn gbin ninu iparun ti o de ba wọn gẹgẹ bi orilẹ ede, ati ninu ijiya ti o tẹle ifọnka wọn lasan ni. Woli naa sọ wipe: “Israeli iwọ ti pa ara rẹ run;” “nitori iwọ ti ṣubu nitori aiṣedeede rẹ.” Hosea 13:9; 14:11. A saba maa n ṣe agbekalẹ ijiya ti a fi bẹ wọn wo gẹgẹ bi aṣẹ taara lati ọdọ Ọlọrun wa. Bayi ni atannijẹ nla naa ṣe n fi iṣẹ ọwọ rẹ pamọ. Nipa fifi orikunkun kọ ifẹ ati aanu Ọlọrun silẹ, awọn Ju jẹ ki a mu aabo Ọlọrun ti o wa lori wọn kuro, a si gba Satani laaye lati dari wọn bi o ti fẹ. Awọn iwa ika ti a wu ni akoko iparun Jerusalẹmu jẹ ifihan agbara igbẹsan Satani lori awọn ti wọn fi ara wọn si abẹ iṣakoso rẹ. ANN 12.5

A ko le mọ iye ti a jẹ Kristi fun alaafia ati aabo ti a n jẹgbadun. Agbara ikalọwọko Ọlọrun ni koi ti i jẹ ki iran eniyan o bọ si ọwọ iṣakoso Satani patapata. Awọn alaigbọran ati alailọpẹ ni idi nla lati fi imoore wọn han fun aanu ati ipamọra Ọlọrun ni dida agbara buburu ati agbara ika ẹni ibi ni duro. Ṣugbọn nigba ti eniyan ba kọja odiwọn ipamọra Ọlọrun, a o mu ikalọwọko naa kuro. Ọlọrun ko duro gẹgẹ bi olumuṣẹ idajọ ẹṣẹ fun ẹlẹṣẹ; ṣugbọn a fi awọn ti wọn kọ aanu Rẹ silẹ si ara wọn lati kore ohun ti wọn gbin. Gbogbo itansan imọlẹ ti a kọ silẹ, gbogbo ikilọ ti a gan ti a ko ṣe igbọran si, gbogbo ifẹkufẹ ọkan ti a tẹ lọrun, gbogbo ẹṣẹ si ofin Ọlọrun, jẹ irugbin ti a gbin ti yoo mu ikore ti o daju wa. Ẹmi Ọlọrun ti ẹlẹṣẹ n fi gbogbo igba n kọ silẹ, ni a o mu kuro lọdọ rẹ lẹyin-ọrẹyin, ti ko sì ní sí agbara lati ṣe akoso ero buburu inu ọkan, ko si ni si aabo kuro ninu iwa ika ati ikorira Satani. Iparun Jerusalẹmu jẹ ikilọ nla ti o si lẹrù fun gbogbo awọn ti wọn n fi ẹbun oore ọfẹ Ọlọrun ṣere, ti wọn n kọ ipe aanu Ọlọrun silẹ. Ko si ibi ti a tun ti ri ijẹri ti o yeni yeke nipa ikorira Ọlọrun fun ẹṣẹ, ati nipa ijiya ti o daju ti yoo wa si ori ẹlẹṣẹ. ANN 12.6

Asọtẹlẹ Olugbala nipa ibẹwo idajọ lori Jerusalẹmu yoo ni imuṣẹ miran, eyi ti iparun yẹn jẹ òjiji lasan fun. A le ri iparun aye ti o kọ aanu Ọlọrun silẹ ti o tun tẹ ofin Rẹ loju ninu atubọtan ilu ti a yan yii. Akọsilẹ nipa ijiya eniyan ti aye ti ri ni gbogbo akoko iwa ọdaran ọlọjọ gbọọrọ jẹ eyi ti o banininujẹ. O maa n banilọkanjẹ, o si maa n su ni nigba ti a ba n ro o. Ohun ti o buru jọjọ ni o maa n jẹ atubọtan kikọ aṣẹ Ọrun silẹ. Ṣugbọn iṣẹlẹ ti o buru ju eyi lo ni a ṣe alaye rẹ ninu ifihan nipa ọjọ iwaju. Awọn akọsilẹ atẹyinwa—irukerudo ọlọjọ gbọọrọ ti wọn to lẹsẹẹsẹ, ija, ati idoju ijọba bolẹ, “ogun awọn jagunjagun . . . pẹlu ariwo iporuuru ati aṣọ ti a yi ninu ẹjẹ” (Aisaya 9:5)—kini awọn nnkan wọnyi jasi ni afiwe pẹlu ibẹru ọjọ naa nigba ti a ba mu Ẹmi Ọlọrun ti n káni lọwọ ko kuro patapata lori awọn ẹni buburu, ti ko ni si nibẹ mọ lati dawọ itusita ifẹkufẹ ọkan eniyan ati ibinu gbigbona eniyan duro! Aye yoo ri ni ọna ti koi ti i riri atubọtan iṣakoso Satani. ANN 13.1

Ṣugbọn ni ọjọ naa bii ti akoko iparun Jerusalẹmu, a o gba awọn eniyan Ọlorun silẹ, gbogbo awọn ti a kọ orukọ wọn sinu iwe iye. Aisaya 4:3. Kristi sọ pe Oun n bọ lẹẹkeji lati ko awọn eniyan Rẹ ti wọn jẹ olooto si sí ọdọ ara Rẹ: “Nigba naa ni gbogbo ẹya aye yoo kaanu, wọn yoo si ri Ọmọ eniyan ti yoo maa ti oju ọrun bọ ti Oun ti agbara ati ogo nla. Yoo si ran awọn angẹli Rẹ pẹlu ohùn ipe nla, wọn o si ko gbogbo awọn ayanfẹ Rẹ lati origun mẹrẹẹrin aye jọ, lati ikangun ọrun kan de ekeji.” Matiu 24:30, 31. Nigba naa ni yoo fi ẹmi ẹnu Rẹ pa awọn ti ko ṣe igbọran si iyinrere, yoo si pa wọn pẹlu itansan wiwa Rẹ. 2 Tẹsalonika 2:8. Bi ti Israeli ni igba atijọ, awọn eniyan buburu ni wọn pa ara wọn run; wọn n ṣubu nipasẹ aiṣedeede wọn. Nipa igbesi aye ẹṣẹ, wọn ti pin ara wọn niya pẹlu Ọlọrun to bẹẹ gẹẹ ti iwa buburu fi ba iṣẹda wọn jẹ, ti ifarahan ogo Rẹ yoo jasi ina ajonirun fun wọn. ANN 13.2

Ki awọn eniyan o sọra ki wọn ma baa gbagbe ẹkọ ti a fifun wọn ninu ọrọ Kristi. Bi O ti ki awọn ọmọ ẹyin Rẹ nilọ nipa iparun Jerusalẹmu, ti O fun wọn ni àmì nipa iparun ti o n bọ; ki wọn baa le sa asala; bẹẹ gẹgẹ ni O ṣe ki araye nilọ nipa iparun ikẹyin ti O si fun wọn ni ami wiwa Rẹ, ki gbogbo awọn ti wọn ba fẹ le sa fun ibinu ti n bọ. Jesu sọ wipe: “Àmì yoo wà ninu oorun, ati oṣupa ati irawọ ati lori ile aye idamu fun awọn orilẹ ede.” Luku 21:25; Matiu 24:33; Maku 13:24—26; Ifihan 6:12—17. Gbogbo awọn ti wọn n wo awọn ami wiwa Rẹ wọnyi a “mọ wipe o ti sunmọ etile, ani ni ẹnu ilẹkun.” Matiu 24:33. “Ẹ maa sọna nigba naa” ni ọrọ igbaniniyanju Rẹ. Marku 10:35. A ko ni fi awọn ti wọn ba ṣe igbọran si ikilọ yii sinu okunkun ti ọjọ naa a fi ba wọn lairotẹlẹ. Ṣugbọn fun awọn ti ko ni sọna, “ọjọ Oluwa n bọ wa bi ole ni oru.” 1 Tẹsalonika 5:2—5. ANN 13.3

Araye ko ṣetan lati gba iṣẹ iranṣẹ fun akoko yii bi awọn Ju ko ṣe ti ṣetan lati gba ikilọ Olugbala nipa Jerusalẹmu. Bi o ti wu ki o ri, ọjọ Oluwa yoo de ni airotẹlẹ si awọn alaiwabiọlọrun. Nigba ti aye ba n tẹsiwaju ninu akitiyan rẹ, ti awọn eniyan n fi ara wọn jin fun faaji, fun idoko owo, fun irinkerindo, fun wiwa owó; nigba ti awọn olori ẹsin ba n kokiki itẹsiwaju ati ọlaju inu aye, ti a si fi ọkan awọn eniyan balẹ ninu aabo asan—nigba naa, ni iparun ojiji yoo de si ori awọn alaibikita ati awọn alaiwabiọlọrun bi ole ti n ja ile ti ko ni aabo ni oru ọganjọ, “wọn ki yoo si le sa asala.” Ẹsẹ 3. ANN 13.4