ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA

2/42

ORI KEJI— INÚNIBÍNI NÍ ỌGỌRUN ỌDÚN ÀKỌKỌ

Nigbati Jesu sọ fun awọn ọmọ ẹyin Rẹ nipa atubọtan Jerusalẹmu ati awọn iṣẹlẹ nipa ipadabọ Rẹ lẹẹkeji, O sọ iriri awọn eniyan Rẹ pẹlu lati àkókò ti a o gba A kuro lọwọ wọn, titi fi di akoko ipadabọ Rẹ ninu agbara ati ogo fun idande wọn. Lati oke Olifi Olugbala bojuwo ìjì ti yoo kọlu ijọ apostoli; ni wiwo ọjọ iwaju láwòfín, oju Rẹ ri ni kedere awọn iji nla apanirun ti yoo kọlu awọn atẹle Rẹ ni akoko okunkun ati inunibini ti n bọwa. Ninu awọn ọrọ ṣoki ti itumọ wọn banilẹru O sọ nipa ohun ti awọn alaṣẹ aye yii yoo ṣe si ijọ Ọlọrun. Matiu 24:9, 21, 22. Awọn atẹle Kristi gbọdọ rin oju ọna irẹni silẹ, itiju ati ijiya kan naa ti Ọga wọn rin. A o fi iru iṣọta kan naa ti a fihan fun Olugbala araye han fun gbogbo awọn ti wọn ba gbagbọ ninu orukọ Rẹ. ANN 14.1

Itan ijọ akọkọ ṣe ijẹri si ọrọ Olugbala. Awọn agbara ile aye ati ti ipo oku kọ oju ija si Kristi ninu awọn atẹle Rẹ. Ẹsin ibọriṣa ri wipe bi iyinrere ba fi le ṣegun, a o gba awọn tẹmpili ati pẹpẹ oun kuro; nitori naa o lo awọn agbara rẹ lati pa ẹsin Kristẹni run. A tan iná inunibini silẹ. A gba ohun ìní awọn Kristẹni kuro lọwọ wọn, a si lé wọn kuro ninu ile wọn. Wọn “fi ara da wahala ijiya nla.” Heberu 10:32. Wọn “ri idanwo ẹlẹya lile ati ina, ati ju bẹẹ lọ ti ìdè ati ẹwọn.” Heberu 11: 36. Ọpọ awọn eniyan ni wọn fi ẹjẹ wọn ṣe ami si ijẹri wọn. Ọlọla ati ẹru, ọlọrọ ati otosi, ọmọwe ati alaimọkan, gbogbo wọn ni a pa lapapọ lailaanu. ANN 14.2

Awọn inunibini wọnyi, bẹrẹ labẹ Nero ni akoko ijẹriku Pọlu, o tẹsiwaju fun ọpọ ọdun, nigba miran ọwọ rẹ a silẹ, nigba miran a gbona janjan. Awọn ẹsun iwa ọdaran ti o buru jai ni a fi n kan awọn Kristẹni lọna eke, wọn a si sọ wipe awọn ni wọn fa orisirisi awọn ajalu nla—iyan, ajakalẹ arun ati ilẹ ríri. Bí wọn ti di ẹni ti gbogbo ilu korira ti wọn si n funra si, awọn olofofo ṣetan lati fi alaiṣẹ han nitori owo. A da wọn lẹbi bi aṣọte si ijoba, ẹta ẹsin ati iyọnu laarin awujọ. Ọpọlọpọ wọn ni a ju si awọn ẹranko buburu tabi ti a sun nina láàyè ní awọn gbọngan igbafẹ. A kan awọn miran mọ agbelebu; a da awọ ẹranko buburu bo awọn miran, a wa ju wọn sinu ibi iṣere ki aja baa le fa wọn ya. Ijiya wọn ni a saba maa fi n ṣe ohun igbafẹ to ga julọ nibi ayẹyẹ ara ilu. Ọpọ eniyan ni wọn pejọ lati jẹ igbadun iṣẹlẹ naa ti wọn yoo si fi atẹwọ ati ẹrin dahun si ikerora iku wọn. ANN 14.3

Bi ẹran ijẹ ni a ṣe maa n le awọn atẹle Kristi kiri ni ibikibi ti wọn ba sa si fun aabo. A fi ipa mu wọn lati wa aabo ninu ibi isọdahoro ti o farasin. “Alaini, ẹni ti a n pọn loju, ati ẹni ti a n da loro; (awọn ti aye ko yẹ fun:) wọn rin kiri ninu aṣalẹ, ati lori oke ati ninu ibugbe awọn ẹranko, ati iho abẹ ilẹ.” Ẹsẹ 37, 38. Awọn ibi isinku—si abẹ ilẹ di ibugbe fun ọpọlọpọ. Awọn iho gigun ti a gbẹ gba inu ilẹ ati apata wa labẹ awọn oke lẹyin ilu Romu; iho ilẹ naa ṣokunkun, o si gun ni ọpọlọpọ ibusọ kọja odi ilu. Ninu awọn ibi ifarapamọsi abẹ ilẹ wọnyi ni awọn atẹle Kristi n sin oku wọn si; nibi si ni wọn maa n sa si nigba ti a ba funra si wọn tabi ti a ba fi ofin dè wọn. Nigba ti Afun-ni-ni ẹmi ba ji awọn ti wọn ti ja ija rere dide, ọpọ awọn ajẹriku Kristi ni yoo jade wa lati awọn iho to ṣokunkun wọnyi. ANN 14.4

Awọn ajẹri fun Jesu wọnyi pa igbagbọ mọ lailabawọn labẹ inunibini to gbona janjan. Bi o tilẹ jẹ wipe wọn ko ni anfani lati ri itura kankan, wọn ko ri imọlẹ oorun, ti wọn fi ibi okunkun, sugbon ti o ni alaafia ṣe ibugbe wọn, wọn ko ṣe aroye kankan. Wọn gba ara wọn niyanju pẹlu ọrọ igbagbọ, suuru, ati ireti lati fi ara da ijiya ati ipọnju. Ipadanu gbogbo ibukun aye ko le mu ki wọn kọ igbagbọ wọn ninu Kristi silẹ. Idanwo ati inunibini tilẹ n mu wọn sunmọ isinmi ati ere wọn si ni. ANN 14.5

Bii awọn iranṣẹ Ọlọrun ti igbaani, ọpọlọpọ ni a “ni a dá lóró, ti wọn kọ lati gba idasilẹ; ki wọn baa le ri ajinde ti o dara julọ gba.” Ẹsẹ 35. Awọn wọnyi ranti ọrọ Ọga wọn wipe, nigba ti a ba n ṣe inunibini si wọn nitori Kristi, ki wọn kun fun ayọ gidigidi, nitori pupọ ni ere wọn ni ọrun; nitori bẹẹ gẹgẹ ni a ṣe inunibini si awọn woli ti wọn wa ṣaaju wọn. Wọn yọ nitori pe a ka wọn yẹ lati jiya nitori otitọ, orin iṣẹgun si ti inu ina ti n jo goke wa. Ni wiwoke pẹlu igbagbọ wọn ri Kristi ati awọn angẹli Rẹ ti wọn rọgbọku lori odi ọrun, wọn n wo wọn pẹlu ifẹ ọkan giga, ti wọn si n fiye si idurosinsin wọn pẹlu inu didun. Ohùn kan kọ si wọn lati itẹ Ọlọrun wa wipe: “Jẹ olootọ titi de oju iku, Emi yoo si fun ọ ni ade iye.” Ifihan 2:10. ANN 14.6

Pabo ni akitiyan Satani lati fi iwa ipa pa ijọ Ọlọrun run jasi. Ijakadi nla naa ninu eyi ti awọn ọmọ ẹyin Jesu padanu ẹmi wọn ko dopin pẹlu awọn a-gbé-àsíá olootọ ti wọn ṣubu lẹnu iṣẹ wọn yii. Nipa iṣubu wọn ṣẹgun. A pa awọn oṣiṣẹ Ọlọrun, ṣugbọn iṣẹ Rẹ n rọra n tẹsiwaju. Iyinrere n tẹsiwaju lati tan kalẹ, iye awọn ti wọn gba a gbọ si n pọ si. O wọ awọn ẹkun ti asia ijọba Romu ko le wọ. Kristẹni kan sọ bayi nigba ti o n jiroro pẹlu awọn alaṣẹ ti wọn jẹ abọriṣa ti wọn jẹ ki inunibini o tẹsiwaju, wipe: Ẹ le “pa wá, e le fi iya jẹ wa, e le dá wa lẹbi. . . . Aiṣododo yin jẹ ẹri si wipe a wa ni ailẹṣẹ. . . . Bẹẹ ni iwa ika yin ko ran yin lọwọ.” O jẹ ipe ti o lagbara lati mu ki awọn miran o ri ohun ti wọn gbagbọ. “Bi ẹ ṣe n ge wa lulẹ, bẹẹ ni iye wa n pọ si. Irugbin ni ẹjẹ awọn Kristẹni jẹ.” ANN 15.1

Ọpọlọpọ ni a ju sinu tubu tabi ti a pa, ṣugbọn awọn miran dide lati rọpo wọn. Awọn ti a pa nitori Kristi jẹ ti Rẹ, O si ka wọn si aṣẹgun. Wọn ti ja ija rere, wọn yoo si gba ade ogo nigba ti Kristi ba de. Ijiya ti awọn Kristẹni n farada mu wọn sunmọ ara wọn ati Olurapada wọn si. Apẹẹrẹ igbesi aye wọn ati ijẹri iku wọn jẹ ẹri ti o duro ṣinṣin si otitọ; nibi ti a ko si lero rara, awọn atẹle Satani n fi iṣẹ re silẹ wọn si n duro si abẹ asia Kristi. ANN 15.2

Nitori naa Satani pero lati doju ija kọ ijọba Ọlọrun daradara nipa ríri asia rẹ sinu ijọ Kristẹni. Bi a ba le tan awọn atẹle Kristi jẹ ki a si mu ki wọn ṣe ohun ti ko dun mọ Ọlọrun ninu, agbara wọn, igboya wọn ati iduroṣinṣin wọn a baku, wọn a si ṣubu bi ẹran ijẹ. ANN 15.3

Alatako nla wa ṣa ipa lati fi ọgbọn ẹwẹ gba ohun ti o baku lati fi agbara gba. Inunibini dawọ duro, ṣugbọn a fi ẹwa ọrọ ati ọla aye, eyi ti o lewu rọpo. Awọn abọriṣa gba die ninu igbagbọ Kristẹni, nigba ti wọn kọ awọn otitọ yooku ti wọn ṣe pataki silẹ. Wọn jẹwọ lati gba Jesu gẹgẹ bi Ọmọ Ọlọrun ati lati gbagbọ ninu iku ati ajinde Rẹ, ṣugbọn wọn ko ni idalẹbi ẹṣẹ, wọn ko si rí idi fun ironupiwada tabi iyipada ọkan. Pẹlu bi wọn ti gba diẹ ninu igbagbọ Kristẹni, awọn naa sọ wipe ki wọn gba diẹ lara igbagbọ wọn, ki gbogbo wọn le wa ni irẹpọ lori ipele igbagbọ ninu Kristi. ANN 15.4

Ni akoko yi ijọ wa ninu ewu ti o banilẹru. Ibukun ni ọgba ẹwọn, ifiyajẹni, ina ati ida jẹ bi a ba fi we eleyi. Apa kan lara awọn Kristẹni duro gbọin, wọn wipe wọn ko le ba aye rẹ. Awọn miran fara mọ jijuwọsilẹ, tabi titun diẹ lara awọn ohun ti wọn gbagbọ ṣe ki wọn si darapọ mọ awọn ti wọn gba diẹ lara igbagbọ Kristẹni, wọn sọ wipe, eyi le jẹ ọna fun wọn lati yipada patapata. Akoko yii jẹ akoko iporuuru ọkan nla fun awọn atẹle Kristi tootọ. Labẹ afarawe Kristẹni, Satani n ti ara rẹ wọ inu ijọ, lati ba igbagbọ rẹ jẹ ati lati yi ọkan wọn kuro ninu ọrọ otitọ. ANN 15.5

Ọpọlọpọ awọn Kristẹni ni wọn gba lẹyin-ọrẹyin lati fa ọwọ odiwọn sisalẹ, iṣọkan wá wà laarin ẹsin Kristẹni ati ẹsin ibọriṣa. Bi o tilẹ jẹ wipe awọn abọriṣa sọ wipe wọn ti yi pada, ti wọn si da ara pọ mọ ijọ, wọn si dirọ mọ aṣa ibọriṣa wọn, wọn tilẹ yi ohun ti wọn n jọsin si ere Jesu, ani ti Maria ati ti awọn eniyan mimọ ni. Bayi ni iwukara ẹlẹgbin ibọriṣa ti a mu wọ inu ijọ ṣe tẹsiwaju ninu iṣẹ buburu rẹ. A ko awọn ikọni ti ko bojumu, ilana isin eke, ati aṣa ibọriṣa wọ inu igbagbọ ati ijọsin rẹ. Bi awọn atẹle Kristi ṣe n darapọ mọ awọn abọriṣa, bẹẹ ni ẹsin Kristẹni ṣe n dibajẹ, ti ijọ si padanu iwa mimọ ati agbara rẹ. Ṣugbọn awọn miran wà ti awọn itanjẹ wọnyi ko ṣi lọna. Wọn si jẹ olootọ si Ipilẹsẹ otitọ, wọn si jọsin Ọlọrun nikan ṣoṣo. ANN 15.6

Oriṣi isọri meji ni o saba maa n wa laarin awọn ti wọn pe ara wọn ni atẹle Kristi. Nigba ti isọri kan n ṣe ayẹwo igbesi aye Olugbala ti wọn si n fi tọkantọkan wá lati tun ibaku wọn ṣe ati lati wà ni ibamu pẹlu Apẹrẹ naa, isọri keji kọ awọn otitọ ti wọn han kedere ti wọn fi awọn aṣiṣe wọn han silẹ. Ani nigba ti ijọ wa ni ipo ti o dara julọ ki i ṣe gbogbo awọn ti wọn wa ninu rẹ ni wọn jẹ olootọ, oniwamimọ, ati olododo. Olugbala kọ ni wipe a ko gbọdọ gba awọn ti wọn mọọmọ n da ẹṣẹ sinu ijọ; sibẹ O da ara Rẹ pọ mọ awọn ti iwa wọn kò pé, O si fun wọn ni anfani ikọni ati apẹrẹ Rẹ, ki wọn baa lè ni oore ọfẹ lati ri awọn aṣiṣe wọn ki wọn si ṣe atunṣe. Lara awọn apostoli mejila ni Judasi ọdalẹ wà. A ko gba Judasi nitori pe iwa rẹ ko pe, ṣugbọn pẹlu iwa aipe rẹ. A so o pọ mọ awọn ọmọ ẹyin ki o le mọ ohun ti iwa Kristẹni i ṣe nipasẹ ẹkọ ati apẹrẹ Kristi, ki o si ri awọn aṣiṣe rẹ, ki o le ronupiwada, ati pẹlu oore ọfẹ Ọlọrun, ki o fọ ọkan rẹ mọ nipa “ṣiṣe igbọran si otitọ.” Ṣugbọn Judasi ko rin ninu imọlẹ ti a fi oore ọfẹ gbà laaye lati tan si i. Nipa dida ẹṣẹ o pe idanwo Satani wá. Eyi ti o buru ninu iwa rẹ ni okun ti o pọ si. O fi ọkan rẹ silẹ fun iṣakoso agbara okunkun, inu bi nigba ti a bá bá aṣiṣe rẹ wi, bayi ni o ṣe ṣe titi ti o fi wu iwa buburu ni fifi Ọga rẹ han. Bẹẹ gẹgẹ ni awọn ti wọn fẹran iwa buburu labẹ ijẹwọ iwabiọlọrun ṣe n korira awọn ti wọn n damu alaafia wọn nipa dídá iwa ẹṣẹ wọn lẹbi. Nigba ti aaye bá gbà wọn, bii Judasi, wọn yoo fi awọn ti wọn ba wọn wi fun rere wọn han. ANN 15.7

Awọn apostoli ṣe alabapade awọn ti wọn jẹwọ iwabiọlọrun ṣugbọn ti wọn fẹran ẹṣẹ labẹlẹ ninu ijọ. Anania ati Safira wu iwa atannijẹ, wọn n dibọn bi ẹnipe wọn fi gbogbo rẹ sile fun Ọlọrun, nigba ti wọn fi ojukokoro kó diẹ pamọ fun ara wọn. Ẹmi otitọ fi bi awọn alafẹnujẹ yii ti ri gan-an han, idajọ Ọlọrun si mu abawọn ẹlẹgbin yii kuro ninu ìwà-ní-mímọ ijọ. Ẹri si Ẹmi Kristi ti n da nnkan mọ ninu ijọ jẹ ẹru fun awọn alagabagebe ati oniwa buburu. Wọn kò lè wà ni ibaṣepọ pẹlu awọn ti wọn fi igba gbogbo jẹ aṣoju Kristi ni iwa ati ìṣe; bi idanwo ati inunibini ṣe dé si awọn atẹle Rẹ, awọn ti wọn ṣetan lati kọ ohun gbogbo silẹ nitori otitọ nikan ni wọn fẹ lati di ọmọ ẹyin Rẹ. Niwọn igba ti inunibini tẹsiwaju, ijọ wa ni mimọ. Ṣugbọn bi o ti dáwọ duro, awọn eniyan ti ifọkansin ati iṣododo wọn kò kún tó darapọ mọ wọn, ọna si ṣi silẹ fun Satani lati ri ibudo. ANN 16.1

Ṣugbọn ko si ibaṣepọ laarin Ọmọ Alade imọle ati ọmọ alade okunkun, bẹẹ ni ko le si ibaṣepọ laarin awọn atẹle wọn. Nigbati awọn Kristẹni gba lati ni ibaṣepọ pẹlu awọn ti wọn ko yipada kuro ninu ẹsin ibọriṣa tan, wọn wọ oju ọna ti o n lọ jinna si otitọ. Inu Satani dun wipe oun tan ọpọ ninu awọn atẹle Kristi jẹ. O wa lo agbara rẹ lori awọn wọnyi daradara, ó sì mí si wọn lati ṣe inunibini si awọn ti wọn jẹ olootọ si Ọlọrun. Ko si ẹni ti o ni oye lati ṣe atako igbagbọ Kristẹni tootọ bi awọn ti wọn ti fi igba kan ri jẹ olugbeja rẹ; awọn Kristẹni ti wọn fa sẹyin wọnyi, ní dídarapọ mọ awọn abọriṣa ti ko yipada tan, wa kọ oju ija wọn si awọn kókó ti wọn ṣe pataki ninu awọn ikọni Kristi. ANN 16.2

Awọn ti wọn fẹ jẹ olootọ wa nilo lati ṣe giri bi wọn ba fẹ duro gbọin lati tako itanjẹ ati iwa eeri ti a n wọ ni aṣọ mimọ ti a si n mu wọ inu ijọ. A kọ Bibeli silẹ gẹgẹ bi òdiwọn igbagbọ. A pe ikọni nipa ominira ẹsin ni ẹkọ odi, a korira awọn ti wọn gbagbọ ninu rẹ, a sì fi ofin de wọn. ANN 16.3

Lẹyin ijakadi gbigbona ọlọjọpipẹ, awọn olododo perete pinnu lati maṣe ni ibaṣepọ kankan pẹlu ijọ apẹyinda bi o ba kọ lati ya ara rẹ kuro ninu èké ati ibọriṣa. Wọn ri wipe iyapa ṣe pataki bi wọn ba fẹ ṣe igbọran si ọrọ Ọlọrun. Wọn ko gbọdọ ni ifarada fun aṣiṣe ti o lewu fun ọkan wọn, ki wọn si fi apẹẹrẹ ti yoo ṣe ijamba fun arọmọdọmọ wọn lelẹ. Wọn ṣetan lati ṣe ohunkohun ti o ba wà ni ibamu pẹlu igbọran si Ọlọrun lati le ri alaafia ati iṣọkan; ṣugbọn wọn ro wipe alaafia ọun á ti wọn jù bi o ba nilo ki wọn pa igbagbọ wọn tì. Bi o ba jẹ wipe nipa fifa otitọ ati ododo sẹyin nikan ni a file ri iṣọkan, ẹ jẹki iyatọ o wà, ani ogun pẹlu. ANN 16.4

Ì ba dara fun aye ati ijọ bi iru ẹmi ti o n dari awọn ọkan ti wọn duro ṣinṣin wọnyi ba le sọji ninu ọkan awọn eniyan Ọlọrun. Ainibikita ti o banilẹru ni awọn eniyan ni si awọn ikọni ti wọn jẹ opomulero igbagbọ Kristẹni. Èrò naa n gbilẹ kan wipe wọn ko ṣe pataki to bẹẹ. Ifasẹyin yii n fi okun kún ọwọ awọn aṣoju Satani, ti o fi jẹ wipe awọn ẹkọ èké ati itanjẹ buburu eyi ti awọn olootọ latẹyinwa fi ẹmi wọn wewu lati doju ija kọ ati lati tu asiri wọn ni ọpọlọpọ ti wọn pe ara wọn ni atẹle Kristi n fi oju rere wò. ANN 16.5

Awọn Kristẹni akọkọ jẹ eniyan pataki nitootọ. Igbesi aye àilabawọn wọn ati igbagbọ ti ko yẹsẹ wọn jẹ ibawi àtìgbàdégbà to n damu alaafia awọn ẹlẹṣẹ. Bi wọn ko tilẹ pọ niye, ti wọn ko ni ọrọ, ipò, tabi oyè ni àwujọ wọn jẹ ìpayà fun awọn aṣebi nibikibi ti a ba ti mọ iwa ati ikọni wọn. Nitori idi eyi awọn eniyan buburu korira wọn, ani bi Keeni alaiwabiọlọrun ti korira Abeli. Fun idi kan naa ti Keeni fi pa Abeli ni awọn ti wọn n wá lati dawọ idanilẹkun Ẹmi Mimọ duro ṣe pa awọn eniyan Ọlọrun. Fun idi kan naa ni awọn Ju ṣe kọ Olugbala silẹ ti wọn si kan-An mọ agbelebu—nitori ìwà ailabawọn ati iwa mimọ Rẹ jẹ ibawi atigbadegba fun imọtara-ẹni-nikan ati iwa ibajẹ wọn. Lati àkoko Kristi titi di isinsinyii, awọn atẹle Rẹ nitootọ si n ru ẹmi ikorira ati atako awọn ti wọn fẹran ti wọn si n rin ni ọna ẹṣẹ soke. Bawo wa ni a ṣe le pe iyinrere ni iṣẹ iranṣẹ alaafia? Nigba ti Aisaya so asọtẹlẹ nipa ìbí Mesaya, o pe E ni “Ọmọ Alade Alaafia.” Nigba ti awọn angẹli kede fun awọn oluṣọ aguntan wipe a bi Kristi, wọn kọrin ni oju ofurufu Betlẹhẹmu wipe: “Ogo ni fun Ọlọrun ni oke ọrun, ati ni ori ilẹ aye, alaafia, ifẹ inu rere si eniyan.” Luku 2:14. O dabi ẹnipe iyatọ wà laarin awọn ọrọ asọtẹlẹ wọnyi ati awọn ọrọ Kristi: “Emi kò wá lati ran alaafia, bikoṣe idà.” Matiu 10:34. Ṣugbọn bi o ba yeni daradara, awọn mejeeji wa ni ìbámu ti o peye pẹlu ara wọn. Iyinrere jẹ iṣẹ iranṣẹ alaafia. Ẹsin Kristẹni jẹ ilana ti i ba tan alaafia, iṣọkan, ati idunnu kaakiri gbogbo aye bi a ba gba a ti a si ṣe igbọran si. Ẹsin Kristi yoo so gbogbo awọn ti wọn ba gba ikọni rẹ pọ di ara kan. Erongba Jesu ni lati ba awọn eniyan laja pẹlu Ọlọrun ati laarin ara wọn. Ṣugbọn gbogbo aye lapapọ wa labẹ akoso Satani ọta Jesu ti o ga julọ. Iyinrere fun wọn ni ẹkọ ìgbé aye ti o yatọ patapata si iwa ati ifẹ ọkan wọn, wọn si dide ni iṣọtẹ si. Wọn korira iwa ailabawọn ti o fi ẹṣẹ wọn han ti o si ba wọn wi, wọn ṣe inunibini si awọn ti wọn ni ki wọn pa akọsilẹ mimọ ati otitọ rẹ mọ, wọn si pa wọn run. Ni ọna yii—nitori ti awọn otitọ nla rẹ n fa ikorira ati ija—ni a fi pe iyinrere ni idà. Ètò ti ko yeni ti o gba awọn olododo laaye lati jiya inunibini ni ọwọ awọn eniyan buburu fa iporuuru ọkan nla fun awọn ti wọn jẹ alailera ninu igbagbọ. Awọn miran ṣetan lati sọ igboya wọn ninu Ọlọrun nu nitori ti O gba awọn eniyan buburu laaye lati ṣe rere, nigba ti agbara ika wọn n fiya jẹ awọn ẹni rere ati eniyan mimọ ti o si n da wọn loro. A maa n beere, bawo ni Ẹni ti O jẹ olododo ati alaanu ti agbara rẹ ko lopin ṣe le fi aaye gba iru iwa aisotitọ ati ifiyajẹni yii. A ko ni ohunkohun i ṣe pẹlu ibeere yii. Ọlọrun ti fun wa ni ẹri ti o pọ to nipa ifẹ Rẹ, a ko si gbọdọ ṣe iyemeji nipa iwa rere Rẹ nitori pe a ko ni oye iṣọwọṣiṣẹ ipese Rẹ. Nigba ti O ri iyemeji ti yoo kọlu ọkan awọn ọmọ ẹyin Rẹ ni akoko okunkun ati idanwo, Olugbala sọ fun wọn wipe: “Ẹ ranti ohun ti Mo sọ fun yin, iranṣẹ ki i tobi ju oluwa rẹ lọ. Bi wọn ba ṣe inunibini si Mi, wọn yoo ṣe inunibini si yin pẹlu.” Johanu 15:20. Ìyà ti Jesu jẹ fun wa ju eyi ti eyikeyi ninu awọn atẹle Rẹ yoo jẹ lati ọwọ awọn eniyan buburu lọ. Awọn ti a pe lati fi ara da ijiya ati ijẹriku tilẹ n tẹle apẹẹrẹ Ọmọ Ọlọrun lasan ni. ANN 17.1

“Ọlọrun ko fi ileri Rẹ jafara.” 2 Peteru 3:9. Ko gbagbe bẹẹ ni kò kọ awọn ọmọ Rẹ silẹ; ṣugbọn O gba awọn eniyan buburu laaye lati fi bi wọn ti jẹ nitootọ han, ki a ma baa tan ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣe ifẹ Rẹ jẹ nipa wọn. Siwaju si, a n ju awọn olododo sinu ina ijiya ki a baa le fọ wọn mọ; ki apẹẹrẹ wọn le jẹ ki awọn miran o mọ itumọ igbagbọ ati iwabiọlọrun; ati ki iwa aiyẹsẹ wọn baa le jẹ ibawi fun awọn alaiwabiọlọrun ati alaigbagbọ. ANN 17.2

Ọlọrun gba awọn eniyan buburu laaye lati ṣe rere ati lati fi ikorira wọn si Oun han ki gbogbo eniyan baa le ri otitọ ati aanu Ọlọrun ninu iparun wọn nigba ti wọn bá kún ago ẹṣẹ wọn. Ọjọ igbẹsan Rẹ n yara bọ kankan, nigba ti gbogbo awọn ti wọn ru ofin Rẹ ti won si fi iya jẹ awọn eniyan Rẹ yoo gba ere ti o tọ si iṣẹ wọn; nigba ti a o fi iya jẹ gbogbo iwa ika ati iwa aiṣododo tí a ṣe si awọn olootọ Ọlọrun gẹgẹ bi eyi ti a ṣe si Kristi funra Rẹ. ANN 17.3

Ohun miran tun wa tí o yẹ ki awọn ijọ ode oni o fi iyè si. Aposteli Pọlu sọ wipe “gbogbo awọn ti yoo gbe igbesi aye iwabiọlọrun ninu Kristi Jesu yoo doju kọ inunibini.” 2 Timoti 3:12. Kini o wa ṣẹlẹ ti o fi dabi ẹnipe inunibini rẹwẹsi? Idi kan ṣoṣo ni wipe ijọ ti da ara pọ mọ agbekalẹ aye nitori naa kò ru àtakò sókè mọ. Ẹsin ti o wọpọ ni ode òni ko ni iwa pipe ati iwa mimọ ti o wa ninu igbagbọ Kristẹni ni akoko Kristi ati awọn apostoli. Nitori ẹmi ibadọrẹ pẹlu ẹṣẹ, nitori pe a ko naani awọn otitọ nla ti wọn wa ninu ọrọ Ọlọrun, nitori pe ẹmi iwabiọlọrun ko wọpọ mọ ninu ijọ, ni o fi dabi ẹnipe esin Kristẹni wa ni iṣọkan pẹlu aye. Ẹ jẹ ki isọji igbagbọ ati agbara ijọ akoko o wa, ẹmi inunibini yoo sọji, a o si tun ina inunibini tan. ANN 18.1