ISE ISIN ONIGBAGBO

133/273

ORÍ —KEJÌLÁ ÌWÀÁSÙ ÌHÌNRERE E TI BÍBÉLÌ

Èrò Ìbí i Ti Ọ̀run

Èrò láti gbé Bibeli kíkà kalẹ̀ jẹ́ èrò láti ọ̀run. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló wà, àti àwọn ọkùnrin àti àwọn ọbìnrin, tí wọ́n lè kópa nínú ẹ̀ka iṣẹ́ ajíhìnrere. A lè jẹ́ kí àwọn òṣìṣẹ́ tí yóò fẹ́ jẹ́ alágbára eniyan Ọlọrun gbèrú. Nípa ọ̀nà yìí. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn ni wọ́n ti gba ọrọ Ọlọrun; àwọn òṣìṣẹ́ ni a múwá sínú ìfojúrinjú pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà. A gbé Bíbélì lọ sínú àwọn ìdílé, àwọn òtítọ́ mímọ́-ọn RẸ̀ ni a sì mú lọ sí ẹ̀rí ọkàn.Àwọn ènìyàn ni a bẹ̀ láti kà, láti yẹ̀wò, kí wọn sì ṣe ìdájọ́ fúnra a wọn, wọ́n sì gbọdọ̀ wà lábẹ́ ànfààní i ti gbígbà tàbí kíkọ ìfòyehàn láti ọ̀run. Ọlọ́run kò ní gba iṣẹ́ iyebíye tí wọ́n ṣe fún-Un yìí láàyè láti lọ láì lérè.. Yóò dé gbogbo àṣeyọrí yì í ládé pẹ̀lú ìgbìyànjú tí a ṣe pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ní orúkọ ọ RẸ̀.- Gospel Workers, p.192. IIO 141.1

Iṣẹ́ ẹ wa ni a ti fi àmì sí fún wa nípaṣẹ̀ bàbá a wa tí ń bẹ lọ́run.A ní láti gbé Bibeli i wa, kí a lọ láti ṣe ìkìlọ̀ fún aráyé.A ní láti jẹ́ ọwọ́ Ọlọrun tí ń ran ni lọ́wọ́ nínú u gbígba ọkàn là,-àwọn orísun ibi tí ìfẹ́ ẹ RẸ̀ ojoojúmọ́ ti ń sun fún àwọn tí ó ń ṣègbé.- Testimonies, vol.9. p.150. IIO 141.2