ISE ISIN ONIGBAGBO

123/273

ORÍ — KỌNKÀNLÁ IṢẸ́ AJÌHÌNRERE ONÍṢÈGÙN

Iṣẹ́ Àkọ́kọ́ Tí ó Ṣe Pàtàkì

Ní àsìkò iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ RẸ̀, Jésù fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsìkò sílẹ̀ láti wo aláìsàn sàn ju kí ó wàásù lọ.- The Ministry of Healing, p.19 IIO 132.1

Kí àwọn alátúńṣe tòótọ́ tó dé, iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti àwọn oníṣègùn yóò ṣí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀kùn. - Testimonies, vol.7, p.62. IIO 132.2

Ojúlówó iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti oníṣègùn jẹ́ iṣẹ́ alànà sílẹ̀ fún ìhìnrere. Nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti ọ̀rọ̀ àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ oníṣègùn a ní láti wàásù kí a sì ṣe àmúlò ìhìnrere náà.- The Ministry of Healing, p.144. IIO 132.3

Olùgbàlà aráyé fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsìkò sílẹ̀ ó ṣiṣẹ́ láti ṣe àwòtán fún àwọn tí a ni lára kúrò nínú àìsàn-an wọn ju kí Ó wàásù lọ. Àṣẹ ẹ RẸ̀ lẹ́hìn fún àwọn àpóstélì i RẸ̀, àwọn aṣojú u RẸ̀, lórí ilẹ̀ ayé, ni láti gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn kí wọn ba à le è sàn nínú àrùn-un wọn. Nígbà tí Oluwa yóò bá dé, Yóó gbóríyìn fún àwọn tí ó bẹ aláìsàn wò àti àwọn tí wọ́n ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn aláìní nínú ìpọ́njú u wọn.- Testimonies, vol.4, p.225. IIO 132.4

Ó pète e rẹ̀ pé kí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti oníṣègùn ajíhìnrere yóò pèsè ọ̀nà fún ìgbẹ́kalẹ̀ òtítọ́ tí ń gbani là ti àsìkò yìí, - ìpolongo iṣẹ́ ìránṣẹ́ ańgẹ́lì kẹ́ta. Tí wọ́n bá bá ète yìí pàdé, iṣẹ́ ìránṣẹ́ yì í kò ní ṣókùnkùn tàbí kí wọn dá ìlọsíwájú u rẹ̀ dúró.- Testimonies,vol.6, p.293. IIO 132.5

Lákọ́kọ́ kí wọn bá àìní àwọn aláìní tí ó wà fún ìgbà díẹ̀ pàdé, kí wọn sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ohun tí wọ́n nílò níti ara àti àwọn ìrora a wọn, ìwọ yóò sì rí ọ̀nà sí ọkàn, níbi tí ìwọ yóò gbin àwọn èso rere ti ìwà ọ̀run àti ẹ̀sìn sí. - Testimonies, vol.4, p.227. IIO 132.6

Kò sí ohun tí ó tóbi tí yóò fún ohun ẹ̀mí lágbára àti ìmúdàgbà ju ìtara àti èrò tí ó jinlẹ̀, ju kí a ṣàbẹ̀wò kí a sì bá aláìsàn sọ̀rọ̀ àti àwọn tí wọ́n ti sọ ìrètí nù, ràn wọ́n lọ́wọ́ láti le rí ìmọ́lẹ̀ náà àti láti lè jẹ́ kí wọn dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́ ọ wọn nínú u Jésù. - Testimonies, vol.4, pp.75, 76. IIO 132.7