ISE ISIN ONIGBAGBO

79/273

ORÍ — KẸSÀN-ÁN ÌPÈ FÚN ÌTANIJÍ

Pípè tàṣe tàṣẹ

Jẹ́ kí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ ti ìhìnrere lù jákè jádò àwọn ìjọ ọ wa, pè wọ́n lẹ́jọ́ sí iṣẹ́ ẹ gbo-gbo-gbò. Jẹ́ kí àwọn ọmọ ìjọ dàgbà sí i nínú ìgbàgbọ́ kí wọn ni ìtara nípa àwọn olùgbèjà a wọn ọ̀run tí a kò fojú rí,nípasẹ̀ ìmọ̀ èyí tí orísun-un rẹ̀ kò lè gbẹ,láti inú iṣẹ́ ń lá tí wọ́n ti ń kópa,nípasẹ̀ agbára Olùdarí i wọn. Gbogbo àwọn tí wọ́n fi ara a wọn sí abẹ́ ìsàkóso Ọlọ́run,fún ìdarí àti láti tọ́ wọn sọ́nà,wọn kò ní saláì ní òye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe ṣe àkọsílẹ̀ ẹ rẹ̀.Wọn yóò ní ìṣípayá nípasẹ̀ Ẹ̀mí ẹni tí ó kú fún ìyè aráyé,Wọn kì yóò wá bí aláì lágbára tí ó ń tọ́ka sí ohun tí wọn kò lè ṣe mọ́. Pẹ̀lú u gbígbé ìhámọ́ra ọ̀run wọ̀, wọn yóò jáde lọ sógun láti fi tọkàn tọkàn jà fún Ọlọ́run,ní mímọ̀ pé agbára RẸ̀ ti kìíbàátíì yóò bá àìní i wọn pàdé.- Testimonies, vol.7, p. 14. IIO 77.1

Ẹ Jẹ́ kí a jí dìde! ogun náà ń tẹ̀síwájú.Òtítọ́ àti èké ti n súnmọ́ ìjà ìkẹhìn-in wọn. Jẹ́ kí a yan lábẹ́ àsìá ẹ̀jẹ̀ Ọmọ Aládé Ìmmánúẹ̀lì, kí a sì ja ìjà rere, kí a sì gbèrè ayérayé; nítorí pé òtítọ́ ni yóò lékè, a yóò sì ju aṣẹ́gun lọ nípa ẹni tí ó fẹ́ wa. Wákàtí tí o jẹ iyebiye ti ilẹ̀kùn àánú yóò tì ń parí í lọ. Ẹ jẹ́ kí a ríi dájú pé a ṣiṣẹ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun, kí a ba à le yin bàbá a wa ọ̀run lógo, kí ó sì jẹ́ ọ̀nà láti jèrè àwọn ọkàn àwọn tí Krístì kú fún.-Review and Herald, March 13, 1888. IIO 77.2