ISE ISIN ONIGBAGBO
Àṣírí Fùn Àṣeyọrí.
Ìfọwọ́-so-wọ́-pọ̀ nínú u ṣíṣe iṣẹ́ Ọlọ́run ni àṣírí àṣeyọrí i wà.Àṣepapọ̀ tí ó ní ìyàsí mímọ́ gbọdọ̀ wà. Ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú ara ti Krístì gbọdọ̀ kó ipa rẹ̀ nínú iṣẹ́ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí agbára tí Ọlọ́run ti fún un. A gbọdọ̀ rọ́lù papọ̀ tako àwọn ìdènà àti àwọn ìṣòro ní ìfèjìká léjìká, ọkàn sí ọkàn.—Review and Herald, Dec. 12, 1890. IIO 75.1
Tí àwọn onígbàgbọ́ yóò bá fọwọ́-so-wọ́-pọ̀, kí wọn ṣiṣẹ́ ní ìrẹ́pọ̀ lábẹ́ ìṣàkóso agbára kàn, fún àṣeyọrí ohun tí wọ́n ń lépa, wọn yóò sì yí ayé padà.—Testimonies, vol. 9, p. 221. IIO 75.2
Àwọn ańgẹ́lì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìrẹ́pọ̀.Gbogbo igbesẹ ẹ wọn lo wa leto leto. Bí a bá ṣe ṣe àfarawé tímọ́tímọ́ àwọn ọmọ ogun ọ̀run tó bẹ́ẹ̀ ni àṣeyọrí i wọn fún wa yóò ṣe tó. Tí a bá rí i pé kò pọn dandan fún wa láti ní ìrẹ́pọ̀ nínu iṣẹ́ tí àìlétò jẹyọ, tí kò sí ìbáwí, tí kò sì sí àkójọ nínú iṣé e wà, àwọn ańgẹ́lì, tí wọ́n ní ètò tí ó dán mọ́rán tí wọ́n sì ń rìn ní ètò pípé kò lè ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú u wà dáradára. Wọ́n padà pẹ̀lú ìbìnújẹ́, nítorí wọn kò fún wọn ní àṣẹ láti bùkún rúdurùdu, ìdààmú àti àìlétò. Gbogbo ẹni tí ó nífẹ̀ ẹ́ sí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tí àwọn ìránṣẹ́ ẹ ti ọ̀run, gbọdọ̀ ṣiṣẹ̀ ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú u wọn. Àwọn tí wọ́n ní ìtòróró sí láti òkè yóò nínú ìgbìyànjú u wọn yóò gba ètò, ìbáwí, ìṣọ̀kan ti iṣẹ̀, àti nígba náà ni àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run yóò lè fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú u wọn.Ṣùgbọ́n láíláí kọ́ ni àwọn ìránṣẹ́ ọ̀run yóò fọwọ́ sí àì ṣedéédé, rúdurúdu àti àìlétò.—Testimonies, vol. 1, pp. 649, 650. IIO 75.3