ISE ISIN ONIGBAGBO

11/273

ORÍ — KEJÌ ÌPÈ SI ÀWỌN Ọ̀DỌ́

Yíyàn Láti Ọ̀run

Olúwa ti yan àwọn ọ̀dọ́ láti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ọ rẹ̀.-Testimonies, vol.7,p.64 IIO 30.1

Pẹ̀lú àwọn jagun jagun àwọn òṣìṣẹ́ bí àwọn ọ̀dọ́, tí a kọ́ lọ́nà tòótọ́, tí a fún ní agbára, báwo ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti Olùgbàlà tí a kàn mọ́ àgbélébùú, tí ó jíǹde àti ìpadàbọ̀ Olùgbàlà yóò ṣe lọ sí gbogbo ayé.-Education, p.271. IIO 30.2

À ǹ rì ọmọ ogun ti ọ̀dọ́ lónìí tí ó lè ṣe púpọ̀ tí a bá darí i wọn dáadáa tí a sì ń gbà wọ́n níyànjú. A fẹ́ kí àwọn ọmọ wa gba òtítọ́ gbọ́. A fẹ́ kí Ọlọ́run bùkún wọn, a fẹ́ kí wọn kópa nínú ètò tí a gbé kalẹ̀ dáadáa fún ìràn lọ́wọ́ ọ̀dọ́ míràn. Kí a kọ́ wọn dáadáa kí wọn lè jẹ́ aṣojú ti òtítọ́, fún wọn ní ìdí ti ìrètí tí ó wà ní ìkáwọ́ wọn, kí wọn sì bu ọlá fún Ọlọ́run nínú ẹ̀ka kẹ́ka tí wọ́n yẹ lati ṣiṣẹ.-General Conference Bulletin, vol.5,no2,p.24.(Jan.29,30,1893). IIO 30.3