ISE ISIN ONIGBAGBO
Ìtara
Àwon Onígbàgbó tí ó ní ìtara ni a fé, ìtara tí yóò fi ara hàn nípa síse isé. Kò ye kí okàn tí ó ní Kristi ní ìdènà láti jéwó Rè ju bí a se dènà odò Nìágrà láti lo sí ibi tí yóò ti sàn jade.—Testimonies, vol. 2, p. 233. IIO 229.6
Gbogbo eni tí ó bá ti gba Kristi ní Olugbala Rè gbodò wá ànfààní láti sin Olórun. Nígbàtí ó ń se àsàrò nínú okàn rè ohun tí Olórun ti se fún òun, okàn rè yóò tèsíwájú pèlú ìfé aláìlégbé àti èmí ìmoore tí ó kún fún ìyìn lógo. Yóò ní ìtara fífi èmí ìmoore rè hàn nípa fífi gbogbo agbára rè se isé Olórun. Yóò fé láti fi ìfé rè hàn sí Kristi fún ìràpadà rè. Yóò se ojúkòkòrò isé takun-takun òun ìfara-eni-jìn.—The Ministry of Healing, p. 502. IIO 229.7
Isé ń lá pò fún àwon Màtá, pèlú ìtara tí wón ní fún kíkópa nínú isé ìsìn. Sùgbón e jé kí n kókó jókòó pèlú Màríà ní abé esè Jésù. E jé kí Kristi ó ya àwon ìwà aápon, ìmúra kankan àti agbára sí mímó nípasè oore-òfé Rè nígbà náà ni ayé wa yóò wà fún isé rere èyí tí a kò le è ségun.—The Desire of Ages, p. 525. IIO 230.1
Ní orúko Olúwa pèlú ìfaradà tí kìí sú àti èyí tí kìí rè èyí tí Kristi ti fi fún àwon òsìsé Rè ni kí a má mú isé Olúwa tèsíwájú.—Testimonies, vol. 9, p. 25. IIO 230.2
E jé kí àwon òsìsé wa wá àwon ònà àseyorí mìíràn èyí tí ó yàtò sí bí a tí ń se é télè. À ń se isé nínú ayé sùgbón a kò fi ìtara se òpòlopò isé. Tí a bá ní èmí ìtara, àwon ènìyàn yóò ní ìyípadà okàn nípa òtító tí ó wà nínú isé ìránsé wa. Àìlo ònà tuntun àti ìlówóówó okàn tí a fi ń se isé Olórun ń jé kí àwon ènìyàn tí ó wà ní ipò orísirísi máa sá séhìn fún wa, àní àwon tí ó yé kí won rí ìtara àti ìjìnlè wa.—Testimonies, vol. 6, p. 417. IIO 230.3