ISE ISIN ONIGBAGBO

1/273

ISE ISIN ONIGBAGBO

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ

Ní nífẹ̀ẹ́ láti fi àwọn ọwọ́ ọ gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ní pàtàkì jùlọ sórí ìwúlò ohun pàtàkì, àwọn ìlànà, àti èrè e níní ìtara, ìgbìyànjú ajíhìnrere tí a yà sí mímọ́, ni ó darí láti ṣe ìwò káàkiri tí ó jinlẹ̀ lórí àwọn ìwé tí ó ní ìmísí, tí ó sì ní àyọrísí ní kíkójọ pọ̀ ní ọ̀nà tí ó rọrùn, àwọn ọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ ṣe sọ́ ọ gan, tí ó kún ìwé èyí tí ó le è yà sọ́tọ̀ tí a sì le è pè ní Ìwé tí a ṣe àkójọpọ̀ ọ rẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Onígbàgbọ́. IIO 5.1

A kò lè fi ìgbà kankan gbà pé àwọn ojú ewe yì í fún wa ní ìkójọ láti inú àwọn ìwé e ti Ìmọ̀ Ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ lọ́nà tí ó gbòòrò lábẹ́ iṣẹ́ ìsìn onígbàgbọ́, ṣùgbọ́n kìkì i pé wọ́n lè sí ipa ọ̀nà tí ó lọ́rọ̀ àti ọ̀nà tí ó lọ salalu fún ìṣèwádì í, níbi tí onígbàgbọ́ òṣìṣẹ́ le è lọ jinlẹ̀ nínú ohun tí ó jẹ́ ti òtítọ́ nípa ti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ẹ ti ìjèrè ọkàn. IIO 5.2

Nínú u wíwá láti onírúurú orísun ti ẹ̀kọ́, ìtọ́jú tí ó péye ni a ti lò láti fi ṣe ìtọ́jú ìtò lẹ́sẹẹsẹ tí ó péye lórí èrò tí òǹkọ̀wé sọ̀rọ̀ lé lórí. A ní ìrètí pé àwọn àṣàyàn yìí ni a rí pé yóò wúlò fún àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run àti àwọn olórí ní orísirísi ẹ̀ka iṣẹ́ ìjọ, tí gbogbo àwọn ènìyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin yóò sì ṣe àyẹ́sí i rẹ̀ àwọn tí Ẹ̀mí Ajíhìnrere Ń lá a nì ti fọwọ́ kan ọkàn-an wọn, àti àwọn tí wọ́n ti ní “òye àsìkò náà, tí wọ́n mọ ohun tí ó yẹ kí Ísírẹ́lì ti ṣe”. IIO 5.3

Ọpẹ́ pàtàkì ni ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ikọ̀ olùkọ̀wé e ti Ẹ̀ka tí ó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ Ajíhìnrere lábẹ́lé ti Olú Ilé Iṣẹ́ ẹ wa Lágbáyé, àti àwọn ẹ̀ka wọn káàkiri, àti àwọn Òṣìṣẹ́ Onígbàgbọ́ tó ṣẹ́kù, tí wọ́n ti ṣe ìrànlọ́wọ́ tí ó níye lórí nínú kíkà àti fífa ààlà sí àwọn onírúurú ìwé fún àkójọpọ̀, tí àwọn ìmọ̀ràn-an wọn àti ìfọwọ́sí i wọn àti àṣeyọ́rí iṣẹ́ ń lá náà ṣe pàtàkì sí púpọ̀. IIO 5.4

Ẹ̀KA TÍ Ó NÍ Í ṢE PẸ̀LÚ IṢẸ́ AJÍHÌNRERE LÁBẸ́LÉ E TI OLÚ ILÉ IṢẸ́ Ẹ WA LÁGBÁYÉ.