Iṣisẹ Si Ọdọ Kristi
Ohun ti a yẹ ki a s̩e pẹlu Jyemeji
Ọpọ enia, papã awọn ti wọn ba s̩ẹs̩ẹ gbagbọ, ni iyemeji ma nda lamu. Ohun pupọ ni o wa ninu Bibeli ti nwọn ko mọ itumọ tabi ti ko tilẹ ye wọn, Satani a si ma lo ero nwọnyi lati mì igbagbọ wọn wò ninu Iwe Mimọ gẹgẹbi ohun ti a fihan lati ọdọ Ọlọrun wa. Nwọn a mã bẽre pe, “Bawo ni mo s̩e le mọ ọna tõtọ? Bi Bibeli ba jẹ ọrọ Ọlọrun nitõtọ, bawo ni mo s̩e le bọ lọwọ iyemeji ati idamu nwọnyi? IOK 78.1
Ọlọrun ko fi igbakan bere lọwọ enia lati gba ohunkohun gbọ lai fi ẹri to daju fun ni, lori eyiti igbagbọ wa yio simi le. Wiwà lãye Ọlọrun ; iwa Rẹ̀, Ọrọ isotitọ Rẹ̀ ni o simi le ẹri ti o yé ni ketekete ; ẹri na si pọ. Sibẹsibẹ Ọlọrun ko mu ona iyemeji kuro patapata. Igbagbọ wa ni lati simi lori ẹri, ki se lori ifihan ti o tayọ iyemeji. Awọn wọnni to fẹ se otitọ gán, yio ni ọpọlọpọ ẹri lori eyiti igbagbọ wọn yio duro le. IOK 78.2
Ko s̩ẽs̩e fun iye wa lati le ni imọ to pe nipa iwa tabi is̩e Eni Ailopin nã. Si ẹniti oye rẹ ga julọ ati ọmọwe julọ ni Ẹni Mimọ nã yio jẹ ohun ijinlẹ fun lailai. “Iwọ ha le fi awari ri idi Ọlọrun? Jobu 11:7, 8. IOK 78.3
Aposteli Paulu sọ bayi pe “A! ọrọ ati ọgbọn ati imo Ọlọrun! awamaridi idajọ Rẹ̀ ti ri, ona Rẹ̀ si ju awari lo! Romu 11:33. Sugbọn bi o tilẹ je pe, “awọsanmọ ati okunkun yi I ka,” “ododo ati idajọ ni ibujoko ite Rẹ̀” Orin Dafidi 97:2. Awa le moye iwa Rè si wa, ati ohun ti o nmu ibalo wọnyi wa, ki a ba le mo nipa ifẹ ailopin ati ãnu Rẹ̀ ti o dapọ mọ agbara ailopin Rẹ̀. A le moye nipa awon ero Rè de ibiti o ba le s̩e wa ni rere de; ati jubẽlọ, a si ni lati gbẹkẹle Alagbara julọ, ẹniti ọkan Rẹ̀ kun fun ifẹ. IOK 78.4
Ọrọ Ọlorun gẹgebi iwa Olupilẹse mimọ rẹ, nfi awọn ohun ijinlẹ ti ẹda kankan ko le mo ni kikun lai funni. Ona ti ẹs̩ẹ gba wọ aiye, awọ enia ti Kristi gbe wọ nigbati ọ mbo wa sinu aiye; atunbi, ajinde, ati awọn ẹkọ miran ti Bibeli kọni, ni o jẹ ohun ijinlẹ ti o jin ju ohun ti enia le s̩e ilàye re, tabi yeni ni kikun lọ. S̩ugbọn ko si idi rẹ̀ ti a fi nilati s̩iye. meji si Ọrọ Ọlọrun nitoripe a kò lè mọ awọn ohun ijinlẹ õre. ọfẹ Rẹ̀. Ni aiye, ọpọ ohun ijinlẹ ti kò yeni li o yi wa ka kiri Awọn ohun alãye to kere julọ jẹ is̩oro ti ọjọ-gbọn julọ laiye ko lè s̩e ilaye. Nibigbogbo ni awọn ohun iyanu ti o tayọ oye wa wà. Njẹ o ha yẹ ki o yà wa lẹnu pe ninu ohun ti ẹmi nã pẹlu, awọn ohun ijinlẹ wa ti ko le ye wa? Is̩oro na wa ninu ailera ati kikere enia. Ọlọrun ti fun wa ni ẹri ti o to ninu we Mimọ, ati pe a ko gbọdọ siyemeji Ọrọ Rẹ nitoripe a k le mọ gbogbo ohun ijinlẹ ipese Ọlọrun fun awa ẹda Rẹ̀. IOK 78.5
Aposteli Peteru sọ pe. . . “ohun miran ti o soro iye ni gbe wa, eyiti awọn ope ati awọn alaiduro nibikan nlo, bi nwọn ti nlo Iwe Mimọ iyoku si iparun ara wọn.” 2 Peter 3:16. Awọn isoro ti o wà ninu Iwe Mimọ li awọn alaigba otitọ gbọ nlo bi ariyanjiyan ti o lodi si Bibeli ; s̩ugbọn ki a ma ri, nwọn jẹ ẹri imisi rẹ lati ọrun. Bi ko ba sọrọ nipa ti Ọlọrun bikos̩e ohun tio lè ye wa kiakia ; bi titobi ati ọla nla Rẹ ba le ye awọn ẹda Rẹ̀, a je wipe Bibeli ko le ni ẹri didaju as̩ẹ Ọlọrun ninu. Ẹwa ati ijinlẹ awọn ẹkọ ti o fikọni gãn nilati mu ki a gbagbọ pe Ọrọ Ọlọrun ni. IOK 79.1
Bibeli fi otitọ han ni ọna irẹlẹ ati imubadọgba pipe si aini ati ifẹ ọkan enia, ti o jẹ ohun iyalẹnu tabi ogun loju ọjọgbọn julọ, ti o si mu ọkan onirẹlẹ ati ope mọ ọna igbala. Sibẹ awọn ọrọ otitọ ti a sọ lọna irẹlẹ nwọnyi sọrọ nipa awọn ẹko ti o niyi, ti o si ga, ti o si tayọ agbara imoye ti ẹda, ti a fi le gbagbọ nitoripe Ọlọrun ti sọ wọn. Bayi ni a se fi ilana igbala han wa, ki olukuluku ba lè ri is̩is̩ẹ ti yio gbe ni ironupiwada si Ọlọrun, ati ni igbagbọ si Oluwa wa Jesu Kristi, ki a ba le gba wa la ni ọna ti Ọlọrun ti là silẹ; sibẹ labẹ awọn otitọ ti o yeni dãda wọnyi ni awon ohun ijinlẹ wa ti eyiti ns̩e ipamọ Ogo Rẹ̀,—awon ohun ijinlẹ to bori ọkan ni iwadi rẹ̀, sibẹ o si nmisi eniti o ba fi tọkantọkan wa otitọ pẹlu ọwọ ati igbagbọ. Bi o ba ti wa inu Bibeli to, bē̩ni ero rẹ yio mã jinlẹ to pe ọrọ Ọlọrun alãye ni, ọgbọn ori ti ẹda a si foribalẹ niwaju ọla nla ifihan ti Ọlọrun. IOK 79.2
Lati gba pe awọn otitọ nla inu Bibeli ko le ye wa ni kikun ni lati gba pe ero kukuru ti ẹda ko to lati mọ ohun ailopin tan, ati pe enia ti on ti ọgbọn kekere rẹ̀, ko le moye awọn ero Ọlọrun Ọlọgbọn julọ. IOK 79.3
Nitoripe nwọn ko mọ gbogbo ohun ijinlẹ Bibeli, awọn oniyemeji kọ̀ Ọrọ Ọlọrun silẹ; ki se gbogbo awọn ti o jẹwọ pe awọn gba Bibeli gbọ ni nwọn bọ ninu ewu nipa ọrọ yi. Aposteli nã wipe, “Ẹ kiyesara, ara, ki ọkan buburu ti aigbagbọ ki o mase wa ninu ẹnikẹni nyin, ni lilọ kuro lọdọ Ọlọrun alãye.” Heberu 3:12. O yẹ lati kiyesi awọn ẹkọ Bibeli ati lati mã wa “ohun ijinlẹ ti Ọlọrun.” (I Kọrinti 2:10) niwọn igbati a ti fi wọn han ninu Iwe Mimọ. Nigbati “awọn ohun ikọ̀kọ̀ jẹ ti Oluwa Ọlọrun wa.” “ohun ti a fihan jẹ tiwa.” Deut. 29:29. S̩ugbọn is̩ẹ Satani ni lati yi agbara iwadi ọkan enia pada. Igberaga ma ndapọ pẹlu iwadi otito ti O mbẹ ninu Bibeli, tobẹ ti enia ko le mu suru, nwọn a si ka a si itiju bi nwọn ko ba le fi itumọ ibikibi ninu iwe Mimọ yeni debi itẹlọrun ọkan wọn. Ohun itiju nla ni fun wọn lati gba pe Ọrọ imisi Bibeli ko ye wọn. Nwọn ko fẹ fi suru duro titi Ọlọrun yio fi ro pe o yẹ lati fi otitọ na han won. Nwọn ro pe ọgbọn ara wọn to lati le ni oye ọrọ inu Iwe Mimọ, nigbati nwọn ba bàku ni s̩is̩e eyi, nwọn a sẹ ẹniti is̩e olupilẹs̩ẹ rẹ̀. õtọ ni pe awọn ero ati ẹkọ ti o lokiki miran ti a si ro pe a mu jade lati inu Bibeli ko ni ipilẹsẹ ninu ikọni rẹ, ati papa nwọn lodi si igbekalẹ ti ọrọ Olorun. Awọn nkan nwọnyi ti mu iyemeji ati idãmu ba ọpọ enia. Ki se ọrọ Ọlọrun ni o mu eyi wa, bikos̩e iyipada otitọ na lati ọwọ enia. IOK 80.1
Bi o ba s̩ẽs̩e fun enia lati le ni oye pipe nipa Ọlọrun ati is̩ẹ Rẹ̀ gbogbo, nigbana ti a ba ti de ipo yi, nwọn ko ni wadi otitọ mọ, ko ni si idagbasoke ninu imọ, tai ilọsiwaju ninu ero tabi ọkan enia. Ọlọrun ko ni jẹ ẹniti o lọla jù mọ; enia iba si dẹkun ati mà tẹsiwaju nigbati nwọn ba ti de opin imọ ati ilosiwaju. Ẹ jẹki a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ko ri bẹ. Agbara Ọlọrun ko lopin : ninu Rẹ̀ ni “gbogbo is̩ura ọgbọn ati ti imọ” wa. Kolose 2:3. Titi aiyeraiye awọn enia le mã wadi, ki nwọn si mã kẹkọ, sibẹsibẹ nwọn ko le lo is̩ura ọgbọn Ọlọrun, Õre Rẹ, ati agbara Rẹ̀ tan. IOK 81.1
Ifẹ Ọlọrun ni pe ni aiye yi ki otitọ ọrọ Rẹ̀ mã s̩ipaya si awọn enia Rẹ̀. Ọna kans̩os̩o ni a fi ni imọ yi. A le ni oye Ọrọ Ọlọrun nipa imọlẹ Ẹmi Mimọ, nipa eyiti a fi ọrọ nã funni “Ko si ẹnikan ti o mọ ohun Ọlọrun, bikos̩e Ẹmi Ọlọrun.” nitoripe Ẹmi ni nwadi ohun gbogbo, ani ohun ijinlẹ ti Olọrun.” I Kọrinti 2:11, 10. Ileri Olugbala fun awọn atẹle Rẹ̀ ni pe “S̩ugbọn nigbati on, ani Ẹmi otitọ nì ba de, yio tọ nyin si ọna otitọ gbogbo . . . .nitoriti yio gba ninu ti emi, yio si ma sọ ọ fun yin.” Johannu 16:13, 14. IOK 81.2
Ọlọrun fẹ ki enia lo agbara ọgbọn ori rẹ; kikọ ẹkọ inu Bibeli yio si mu ọkan lokun, yio si gbe e ga ju gbogbo ẹkọ miran lọ. Sibẹ a nilati s̩ọra ki a má bã sọ ọgbọn-ori di oris̩a, eyiti o kun fun ailera ati ailagbara to ti ẹda. Bi a ko ba fẹ ki ẹkọ Bibeli farasin fun imọ wa tobẹ ti awọn otitọ ti o hàn kedere ko fi ni lè ye wa, a nilati ni irẹlẹ ati igbagbọ bi ti ọmọ kekere, ki a setan lati kẹkọ, ki a mã bẹbẹ fun iranlọwọ Ẹmi Mimọ. Imọ agbara ati ọgbọn Ọlọrun, ati ailagbara enia lati mọ titobi Rẹ̀ yi, nilati mu wa kun fun irẹlẹ, ki a si s̩i Ọ̀ro Rẹ̀ pẹlu ọwọ, gẹgẹbi enipe a wà niwaju Ọlọrun pẹlu ibẹru mimọ́. Nigbati a ba nkọ́ Bibeli, ọgbọn-ori wa nilati mọ alasẹ ti o ga julo, okan ati imọ wa si ni lati tẹriba fun Eni nla na tì ijẹ́ “EMI NI.” IOK 81.3
Awọn nkan miran wa ti o soro ti o si farasin ti Ọlọrun yio fihan fun awọn wọnni ti o nwa imọ nipa wọn. S̩ugbọn laisi itọsọna ti Ẹmi Mimọ nigbagbogo ni ao ma lo Iwe Mimọ ti ao si ma tumọ wọn li ọna àitọ́. Ọna pupọ li o wa ti enia fi nka Bibeli laisi ere kankan, ati nigbamiran ibi ni o ma nti ibẹ̀ jade. Nigbati a ba s̩i Ọrọ Ọlọrun laisi ọwọ ati adura; nigbati ero ati ifẹ kò ba simi le Ọlọrun, tabi ki o ba ifẹ Rẹ̀ mu, ọkan a wá kun fun iyemeji ; ati nipa kikọ Bibeli papa li ai gbagbọ yio wa bẹrẹ si dagba siwaju. Ọta yio si wa jọba lori ero enia, on a si mu itumọ ti ko tọ wa sọkan wa. Nigbakugba ti ọrọ tabi is̩e enia ko ba ti Ọlọrun ẹe dẽde, nibana bi o ti wù ki oluwarẹ lẹkọ to, nwọn le s̩ina ninu imọ wọn nipa Iwe Mimọ, ewu si ni lati gbẹkẹle ilàye wọn. Awọn ti wọn nwa inu Iwe Mimọ lati le ri aidọgba ko ni oju ẹmi. Pẹlu oju ti o s̩e bàibai nwọn yio ri awawi pupọ fun iyemeji ati aigbagbọ ninu awọn ohun ti o rọrun ti o si han gbangba. IOK 81.4
Bi o tilẹjẹpe nwọn nfi pamọ, ohun ti o mu iyemeji ati aigbagbọ wa nipe pupọ ni ifẹ lati dẹ̀s̩ẹ̀. Awọn ikọni ati ohun aigbagbọ-mas̩e ti Ọrọ Ọlọrun, li ọkan igberaga. IOK 82.1
ẹs̩ẹ, kò nifẹ lati feti silẹ si, awọn nwọnni ti kò ba si fẹ mu ọrọ Bibeli s̩ẹ s̩etan nigbagbogbo s̩iyemeji otitọ rẹ. Ki a to de ibi imọ otitọ a nilati ni itara lati mọ otitọ, ati ọkan ifẹ lati gba a gbọ. Gbogbo awọn ti o ba ni iru ẹmi bi eyi lati kọ Bibeli yio ri ẹri pupọ pe ọrọ Ọlọrun ni, nwọn si le ni imọ nipa otitọ rẹ ti o le sọ wọn di ọlọgbọn si igbala. IOK 82.2
Kristi ti wi pe, “Bi ẹnikẹni o ba fẹ lati s̩e ifẹ Rẹ̀, yio mọ niti ẹkọ na.” Johannu 7:17. Dipo ibere ati awawi eke nipa ohun ti kò ye ọ, s̩e akiyesi imọle ti o ntan si ọ lara, iwọ yio si ri imọlẹ ti o tobi gba si i. IOK 82.3
Nipa õre-ọfẹ Kristi, ma s̩e gbogbo is̩ẹ ti a ti fi ye ọ, ao si fun ọ lagbara lati loye ati lati le ẹe nkan wọnni ti o jasi iyemeji fun ọ nisisiyi. IOK 82.4
Ẹri kan wa ti o han si enia gbogbo — ibãse ọmọwe julọ, ati ope julọ — ẹri nã ni iriri. Ọlọrun pe olukuluku enia ki o dan ododo ọrọ Rẹ̀ wo, ati otitọ awọn ileri Rẹ̀. O pas̩ẹ fun wa pe, “tọ Ọ wò, ki o si ri pe, rere ni Oluwa.” Orin 34:8. Dipo ki a simi lori ọrọ awọn ẹlomiran, a ni lati tọwo fun ara wa. O sọ pe, “E bere, e o si ri gba” Johannu 16:24. A o mu awọn ileri Rẹ̀ s̩ẹ. Nwọn ko tase ri; nwọn ko tilẹ le tase lai. Nigbati a ba si sunmọ Jesu, ti a nyọ ninu ẹkún ifẹ Rẹ̀, iyemeji wa ati okunkun wa yio salọ kuro niwaju imọlẹ Rẹ̀. IOK 82.5
Aposteli Paulu sọ bayi pe, “Ẹniti o ti gba wa kuro lọwọ agbara okunkun, ti o si si wa nipo sinu ijọba ayanfẹ Ọmọ Rẹ̀.” Kolose 1:13. Ati ẹnikẹni ti o ba ti re iku kọja bọ sinu iye le fi “edidi di i pe, otitọ li Ọlọrun.” Johannu 3:33. O le jeri pe, “Nigbati mo fẹ iranlọwọ, mo ri ninu Jesu. Olukuluku aini ni a telọrun, a fi onjẹ tẹ ọkan ebi mi lọrun, ati nisisiyi Bibeli jẹ ifihan ti Jesu Kristi fun mi. Iwọ ha bẽre idi rẹ ti mo fi gba Jesu gbọ? Nitoripe On jẹ Olugbala mimọ fun mi. Ẽs̩e ti mo fi gba Bibeli gbọ? Mo ti ri i pe ohùn Ọlọrun ninu ọkan mi li o jasi.” A le ni ẹri nã ninu ọkan ara wa pe otitọ ni Bibeli, pe Kristi jẹ Ọmọ Ọlọrun. A mọ pe a ka tẹle itan asan ti a fi ọgbọn-kọgbọn pe bē̩. Peteru gba awọn ara rẹ ni imọran lati “ma dagba ninu Ore Ọfẹ, ati ninu imọ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi.” 2 Peteru 3:18. Nigbati awọn enia Ọlọrun ba ndagba ninu Ore-Ọfẹ, nwọn yio ma ni imọ pipe si i ninu Ọrọ Rẹ̀. Nwọn yio ri imọlẹ titun ati ẹwa ti mbẹ ninu otitọ Rẹ̀. IOK 82.6
Eyi ti ri bẹ ninu itan ijọ lati aiyebaiye wa, bẹni yio si ma ri titi fi de opin. “S̩ugbọn ipa-ọna awọn olotọ dabi titan imole, ti o ntan siwaju ati siwaju titi di ọsan-gangan.” Owe 4:18. IOK 84.1
Nipa igbagbọ ni a le ma fi wo igba ti mbọ, ki a si di ileri Ọlọrun mu fun idagbasoke oye, imọ enia ki o mã dapọ mọ ti Ọlọrun, ki a si mu olukuluku agbara ọkan wa pade pẹlu Orisun imọlẹ. A le layọ pe gbogbo awọn ohun ti o ti soro fun wa ninu ipèse-silẹ Ọlọrun fun awọn ẹda Rẹ ni ao fihan wa gbangba nigbana ; awọn ohun ti o soro yio ni ilaye nigbana; nibiti ọkan wa gbe ba rudurudu ati ero aipe pade li ao gbe ri idapọ pipe ti o si dara. “Nitoripe nisisiyi awa nriran baibai ninu awojiji ; s̩ugbọn nigbana li ojukoju: nisisiyi mo mọ li apakan; s̩ugbọn nigbana li emi o mọ gẹgẹbi mo si ti di mimọ pẹlu,” I Korinti 13:12. IOK 84.2