Iṣisẹ Si Ọdọ Kristi

1/16

IṢISẸ SI ỌDỌ KRISTI

Ọrọ Jtumọ Ji a fi S̩aju

Orukọ iwe yi fi is̩isẹ rẹ̀ han. O ntọka si Jesu bi ẹnikans̩os̩o na ti O le tán gbogbo aini ọkan enia. O si ntọ ẹsẹ oniyemeji ati ti alais̩edede si “oju ọna alafia.” O si ns̩e amọ̀na awọn ti nlepa ododo ni is̩isẹ kọkan si ipa ọna igbe aiye onigbagbọ, ati sinu ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ibukun eyiti a nri gba nipa tituba ara ẹni patapata ati igbẹkẹle lais̩iyemeji sinu õre-ọfẹ igbala ati sinu agbara ipamọ ẹniti is̩e Ọrẹ: Ọpọlọpọ ọkàn ti ãre ti mu, ti o si ti rẹwẹsi li o ti ri itunu ati ireti gbà nipa ẹkọ iyebiye ti o wà ninu iwe yi, o si ti fi agbara, igbẹkẹle ati ayọ̀ fun ọpọlọpọ awọn atẹle Òluwa wa lati le rin pẹlu igboiya ati palu ayọ̀ ni is̩is̩ẹ Rẹ̀. A si ni ireti pe yio mu iru is̩ẹ irans̩ẹ kanna wá fun ọpọlọpọ awọn ti nfẹ iranlọwọ bayi. IOK 5.1

“Nibẹ jẹki nr’ọna
T’o lọ s’ ọrun.”
IOK 5.2

Bakanna li o ri pẹlu Jakọbu, nigbati ibẹru ẹs̩ẹ mu ki o dabi ẹnipe a ti ké e kuro lọdọ Ọlọrun. O dubulẹ lati simi, “o si la àlá, sikiyesi i, a gbe akasọ kan ka ori ilẹ aiye ti ori rẹ si kan ọrun.” Bayi ni a fi isopọ aiye ati ọrun hàn a, a si sọ ọrọ itunu ati ti ireti fun alarinka na lati ọdo ẹniti o duro ni ténte ori ojiji àkàsò na. Njẹ ki a mas̩aì fi iru iran ọrun bẹ han fun ọpọlọpọ enia bi nwọn ti nkà nipa itan ọna iye yi. IOK 5.3